
Ọjọ Wẹside ana la gbọ pe tirela ako-yọyọ kan, eyi ti nọmba idanimọ ẹ jẹ LND 274 XP lọọ kọlu mọto ti mọlẹbi naa wa, iyẹn mọto ti wọn pe ni Toyota Corolla pẹlu nọmba FGB 940 AA ni nnkan bi aago mẹjọ aarọ.
Lẹsẹkẹsẹ tiṣẹlẹ naa waye la gbọ pe ẹni to wa tirela naa ti na papa bora, ti wọn ko si tii ri titi dasiko ta a kọ iroyin yi tan.
Awọn ẹṣọ oju popona, iyẹn FRSC la gbọ pe wọn pada yọ mọto ayọkẹlẹ naa labe tirela yii.
No comments:
Post a Comment