Bọsun Ọlaniyi,
Abeokuta
Ọba Kehinde Olugbenle, Olu-Ilaro ati Ọba alaye ilẹ Yewa ti ṣeleri pe
gbogbo awọn ọmọ bibi ilẹ Yewa jakejado ni yoo ṣatilẹyin fun adije sipo gomina labẹ
ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọmọba Buruji Kaṣamu ninu idibo to n bọ lọna yii.
Ọba Olugbenle to lewaju awọn Ọba ilẹ naa nibi abẹwo ifọwọsowọpọ ti Kaṣamu
ṣe lọọ bawọn lọjọ Wẹsde onii ṣapejuwe Kaṣamu gẹgẹ bi laanu mẹkunu to mọ ibi ti
bata ti n tawọn araalu lẹsẹ.
Lara awọn Ọba to wa nibẹ ni Eselu tiluu Ọja Ọdan, Oba Ebenezer Akinyẹmi;
Onimẹkọ tiluu Imẹkọ, Ọba Benjamin Oyeditan Ọlanitẹ atawọn Ọba min in lo fi ori
ade sure fun Kaṣamu.
Ninu ọrọ ẹ, Ọba Ebenezer Akinyẹmi sọ pe gbogbo ẹtọ ti awọn awọn adije to
ku ni naa ni Ọmọba Kaṣamu ni gẹgẹ bi ọmọ bibi ilẹ naa, ati pe ọkan awọn balẹ
lori ẹ daadaa.
No comments:
Post a Comment