ÀWA Ò NÍ DÌBÒ FÚN BUHARI BÍ KÒ BÁ FÚN WA NÍ IPÒ MÍNÍSÍTÀ – CAIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, January 19, 2019

ÀWA Ò NÍ DÌBÒ FÚN BUHARI BÍ KÒ BÁ FÚN WA NÍ IPÒ MÍNÍSÍTÀ – CAIA

Ẹgbẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní Coalition of Abuja Indigenous Association CAIA tí i ṣe àgbáríjọpọ̀ àwọn ọmọbíbí olúùlú ilẹ̀ wa, Abuja ti sọ́ ọ di mímọ̀ pé àwọn kò ní dìbò fún Àarẹ Muhammadu Buhari nínú idìbò sí ipò àarẹ tí yóò wáyé ní oṣù tó ń bọ̀.

Wọ́n ní ìdí pàtàkì tí àwọn kò fi ní dìbò fún Àarẹ Muhammadu Buhari sípò Àarẹ ilẹ̀ wa lẹ́ẹ̀kejì ni bí ó ṣe kọ̀ láti mú ìlérí tó ṣe pé òun yóò yan ọ̀kan nínú wọn gẹ́gẹ́ bí mínísítà fún olúùlú ilẹ̀ wa, Abuja sẹ.

Àwọn ẹgbẹ́ náà ni wọ́n sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí wọ́n ń ṣe ìwọ́de aláàáfíà kan níwájú iléeṣé Akọ̀wé Àgbà fún Ìjọba ní Abuja láìpẹ́ yìí níbi tí ogunlọ́gọ̀ wọn ti tú jáde pẹ̀lú àwọn àkọ́lé ifẹ̀hónúhàn tí wọ́n kọ lórísirísi.

Ẹni tó jẹ́ agbénusọ fún ẹgbẹ́ náà, Yunusa Ahmadu Yusuf ṣàlàyé pé ìwọ́dé náà ni wọn ṣe láti fi àìdúnnú wọn hàn lórí ìlérí tí Àarẹ Buhari kọ̀ láti músẹ nínú ìpolongo rẹ̀ ní ọdún 2015 pé òun yóò yan ọmọbíbí ilú náà gẹ́gẹ́ bi mínísítà fún Abuja.

Ó ní àwọn ọmọbíbí ilẹ̀ náà ni wọ́n ti fọwọ́ rọ́ tì sẹ́yìn tí wọn kò si kà wọ́n sí lọ́rọ̀ òṣèlú mọ́ ní ìlú abínibí wọn èyí tó jẹ́ ohun tó ń dùn wọ́n lọ́kàn gidigidi pàápàá bí àfojúsùn wọn lóri ìlérí tí Àarẹ Buhari ṣe kò ṣe wá sí ìmúsẹ.

Wọ́n fi kún un pé Àarẹ Muhammadu Buhari tún kọ̀ láti tẹ̀lẹ́ àṣẹ tí Ilé Ẹjọ́ pa láti fi ọmọìlú sí ipò iṣèjọba pàápàá sí ipò mínísítà náà.

Nígbà tó ń bá wọn sọ̀rọ̀, Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Akọ̀wé Àgbà Ìjọba, Ayuba Musa Barma gbóríyìn fún àwọn olùwọ́de náà fún ifọmọniyànṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣe ìwọ́dé náà ní àlááfíà, pèlú ìdánilójú pé òun yóò tẹ́ pẹpẹ ọ̀rọ̀ náà síwájú Akọ̀wé Ìjọba ẹni tí yóò gbé ẹdùn ọkàn wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn alásẹ.  

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI