AṢIRI PASITỌ TO N FI PATA ṢOOGUN OWO FAWỌN EEYAN TU L’AKURẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 31, 2019

AṢIRI PASITỌ TO N FI PATA ṢOOGUN OWO FAWỌN EEYAN TU L’AKURẸ

Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun

Ọrọ buruku toun tẹrin lọrọ naa jẹ ni tẹṣan ọlọpaa ipinlẹ Ondo niluu Akurẹ lọjọ Wẹside ana nigba ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọgbẹni Fẹmi Joseph foju Adojoh Ojonugwa ti wọn loo ji pata aburo ati pata iyawo aburo e gbe.

Nibẹ ni wọn ti foju Pasitọ ṣọọṣi Sẹlẹ kan naa, Ọlajide Ogunlẹyẹ han pe oun gan an lo ran Adojoh pe ko lọọ wa pata wa lati ba a fi ṣe oogun owo, koun naa le kuro ninu iṣẹ ati oṣi to lo n ba oun ja.

Ohun ta a gbo ni pe lọsẹ to kọja ni iyawo aburo Adojoh ṣa deede wa pata ẹ meji ti, ko si sẹni meji to fura si, bi ko ṣe Adojoh ti wọn ni irin ẹsẹ ko mọ lọ, idi yi to fi lọọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti.

Bawọn ọlọpaa ṣe gbọ ọrọ naa lo mu ki wọn tọpinpin Adojoh, ẹni ọdun marundinlogoji ti wọn lọmọ bibi ipinlẹ Kogi ni, taṣiri ẹ si pada tu si wọn lọwọ, nigba ti wọn maa rii, pata marun ni wọn ba ninu baagi ti wọn ba lọwọ ẹ.

Adojoh naa jẹwọ ẹṣẹ ẹ pe lootọ ni, ati pe kii ṣe pe oun dee de loo ji pata aburo oun, ati pata iyawo aburo oun gbe, o ni Ọlajide Ogunlẹyẹ lo ran oun lati lọọ wa pata wa, nigba toun ko si nibo min in toun yoo ti ri pata lo jẹ koun gba ile aburo oun lọ lati lọọ ji pata iyawo ẹ.

Adojoh sọ pe nigba ti nkan ko lọ deede foun loun tọ Ọlajide lọ lati ṣe iranlọwọ foun, nigba toun si de ọdọ lo loun ti ri ọna abayọ, nibẹ naa lo si ti foun ni nnkan lati gbemi, gbara to loun gbe kinni naa min in loun ko mọ nnkan min in mọ, yatọ si aṣẹ ti Ọlajide pa foun lati lọọ ji pata ka wa.

Iyalẹnu lo jẹ nigba ti Ọlajide funra ẹ n sọrọ, to sọ pe oun ko ri Adojoh ri nigbesi aye oun, ati pe akoba lasan ni Adojoh fẹẹ koba oun. Ọlajije ni lootọ loun maa n bawọn to ba niṣoro dọgbọn si ọrọ aye wọn, ṣugbọn Adojoh ko wa sọdọ oun ri.

O ni ẹgbọn Adojoh loun mọ ri, nitori pe iyẹn ti wa a ba oun lati ra ilẹ, toun ko si ta a fun nitori pe igbo lo fẹẹ fi ilẹ naa gbin, toun ko si nifẹ sii, idi ni yii to lawọn mejeeji fi gbimọ pọ lati koba oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI