Se lo
dabi eni pe ofin orileede Naijiria ko fese mule rara, lori basiri awon iranse
esu ti won nforuko Olorun boju se n fojoojumo tu, paapaa bi iwa agbere ko se
dinku ninu ijo Olorun.
Lojo
Wesde ana nileese sifu difensi nipinle Ondo foju baale ile kan, Ogbeni Josiah
Akinsuyi ta a gbo pe oun ni pasito soosi CAC kan to wa niluu Akure, eni ti won
loo fomodun merindinlogun loyun osu merin han fawon oniroyin.
A gbo
pe o ti pe ti Josiah ti kona fun omo naa ta a foruko bo lasiri, titi tomo naa
fi loyun mon on lowo. Bomo naa se loyun la gbo pe o loo salaye fun Josiah pe
oun ti loyun, sugbon ti pasito naa ni se lawon yoo yo, ati pe ko gbod so
fenikeni.
Nigba tasiri
maa tu, baba omo naa lo sakiyesi awon ayipada kan lara omo e, leyin ayewo ni
won sakiyesi pe omo naa ti loyun, eyi lo fa a tokunrin naa fi gba ileese sifu
difensi lo lati loo fejo sun.
Awon
sifu difensi la gbo pe won loo gbe pasito naa nile, ti won loo si paro pe ko ri
bee, won fe e ba oun loruko je ni, sugbon leyin e lo pada jewo pe looto ni, ati
pe ise esu ni.
Ayewo
tawon sifu difensi se gan an lo je ki won mo pe oyun osu merin lo wa lara omo
naa.
Iwadii
si n lo lowo titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan.
No comments:
Post a Comment