AJỌ INEC TI GBABỌDI FUN WA - ATIKU PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, January 16, 2019

AJỌ INEC TI GBABỌDI FUN WA - ATIKU PARIWO SITA



Adije sipo Aarẹ orileede yi labẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Alaaji Atiku Abubakar ti pariwo sita pe ajọ to n sakoso eto idibo lorileede Naijiria, iyen ajọ INEC ti gbabọdi fawọn oludije ti wọn ri gẹgẹ bi ẹgbẹ alatako sijọba All Progressives Congress, APC.

Ọjọ Tuside ana ni Alaaji Atiku Abubakar sọrọ yi nibi ipolongo idibo Aarẹ to ṣe lọ siluu Oṣogbo, nibẹ lo ti fẹsun kan ajọ INEC pe wọn ti ko gbogbo awọn kaadi idibo alalopẹ tawọn araalu ko lọ ọ gba fawọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC kaakiri orileede yi.

Nitori naa o gbawọn araalu lamọnran pe bi wọn ba ri awọn oju tuntun ti wọn ko ri ri ladugbo wọn lọjọ idibo, ki wọn tete pariwo sita nitori pe ọna lati ṣe madaru lasiko idibo ni ijọba APC n wa.


Ninu ọrọ ẹ, Atiku sọ pe “A ti n gbọ awọn aṣiri nla-nla kan labẹlẹ pe ajọ INEC ti n ko awọn kaadi idibo alalopẹ tawọn eeyan ko tii lọ gba fawọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC, fun idi eyi, bi ẹ ba ri awọn eeyan ti ẹ ko mọ ri lọjọ idibo, ẹ ma gba wọn laye lati dibo lọjọ naa, nitori pe awọn APC ni wọn ran wọn. Ẹ ma si jẹ ki wọn ji ibo yin gbe.”
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI