Ajọ to n gbogunti iwa iṣowo kumọkumọ lorileede Naijiria, EFCC ti fẹsun
jibiti kan akowe ijọba orileede yi tẹlẹ, Babachir Lawal; ọga agba tẹlẹri fun
ajọ National Intelligence Agency, Ayodele Oke ati iyawo ẹ, Arabinrin Fọlaṣade
Oke.
Lọjọ Wẹside onii ni ajọ EFCC fi ẹsun oriṣi mẹwaa ọtọọtọ kan Lawal atawọn
marun un min in, pẹluu ileeṣẹ ẹ, Rholavision Engieneering Ltd niwaju ile ẹjọ
giga tiluu Abuja.
Bẹ o ba gbagbe, lọdun to kọja ni Aarẹ Muhammadu Buhari gbe igbimọ kan
dide, eyi ti igbakeji ẹ, Ọjọgbọ Yẹmi Ọṣinbajo lewaju pe ki wọn ṣewadi ẹsun jibiti
ti wọn fi kan Babachir.
Ẹsun naa bayi la gbọ pe o ti le loṣu mẹẹdogun bayii.
No comments:
Post a Comment