Adíje sípò gómìnà lábẹ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Báyọ̀ Adélabú ti pe àwọn ọ̀dọ́ lórílẹ̀ èdè yìí Nàíjíríà láti jí gìrì sí ojúse wọn gẹ́gẹ́ bi ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ ìdàgbàsókè ìlú pàápàá lọrílẹ̀ èdè Nàíjíríà.
Adélabú,
ẹni tí ó jé ọ̀kan nínú àwọn to sọ̀rọ̀ níbi ètò ìfinimọ̀nà kan tó wáyé nílùú
Ìbàdàn láìpẹ́ yìí, ṣàpèjúwe àwọn ọ̀dọ́ gẹ́gẹ́ bi òpó tó di awùjọ mú tí wọn kò
sì ṣeé fọwọ́ rọ́ tì sẹ́yìn nínú iṣẹ́ ìdàgbàsókè awùjọ.
Ó
ní ipa ribiribi ni àwọn ọ̀dọ́ ń kó nínú ìṣàtúntò ìlú àti ní gbogbo ẹ̀ka tó so
awùjọ ró pàápàá ètò òṣèlú àti iṣèjọba, nítorí náà ni ó fi yẹ kí wọ́n sakítímápa
láti rí i dájú pé wọ́n kó ipa wọn láti mú mùdùnmúdùn ètò iṣèjọba àwarawa kálékáko.
No comments:
Post a Comment