OPE LO YE WA O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 31, 2018

OPE LO YE WA O


Ká dúpẹ lọwọ ẹni tó rí ni tó mọ́jú, àwọn kan ni wọn kò wo ibi tá a wà rárá, idi ni yii ti gbogbo aláṣẹ, apàṣẹ àti Oludasilẹ ileeṣe AWIKONKO MEDIA CHANNEL fi n ki gbogbo ẹyin olólùfẹ́ ẹ wà fún atilẹyin pẹlu àdúrótì i yin.

Gbogbo ẹyin onibara a wa la n ki fún ìfẹ ti é fi n ba wa d'owo pọ. A kò lè dá a ṣe, bẹẹ sì ni a ko le da iroyin wa a kà, bi ko ba sí ẹyin, ko lè sí àwa, eyi la fi n so pe 'E ṣeun lọpọlọpọ'.

Bi a ba ni ka bere sii daruko awon ileese to n ba wa d'owo pọ, a ko ni le e daruko tan, a kò sì fẹ é ṣe ẹnikẹni láì darukọ wọn.

Àjọṣe wa ko ni bajẹ lagbara Ọlọrun. A sì gba a ladura pe ohun gbogbo to n dun onikaluku lokan ni Ọba Aseda yóò dáhùn láì pẹ. Ọta ko ní í yọ wa.

Eyi ni lati fi to o yin leti pe odun 2019 ta a mu yi, ayipada ara-oto ti dé bá ileese wa, idi ni yii to fi je pe bi a ti n mu awọn iroyin wa yóò yato si ti tẹlẹ, ti eyin naa ko sí nii kabamo, nitori pe lori otitọ ati awijare la duro le.

Lati kan sí wa: [email protected] tabi 07012342712, 08064681551.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI