Bi e se n ka iroyin, Onarebu Bolanle Olusegun Gbeleyi to je amugbalegbe Gomina ipinle Ogun lori oro ina mọnamọna (Consultant to the Governor on Power) ti kede sita pe oun ti kuro ninu ẹgbẹ oselu APC lòó darapo mo egbe oselu Allied Peoples' Movement, APM.
Ninu atejade ti Onarebu Gbeleyi ko ranṣẹ s'awọn alatileyin e, eyi to fi eda é ranṣẹ s'AWIKONKO laaro onii lo ti je ko di mi mo pe ki ipinu lati jade dupo lati loo soju awon eeyan oun nile igbimo asofin agba niluu Abuja lodun 2019 lo je koun gbé ìgbésẹ naa.
Onarebu Gbeleyi so pe kii se pe oun dee de fegbe oselu APC sile, bi ko se ti iwa magomago to n lo ninu egbe naa, lo je koun atawon ọmọ ẹgbẹ naa meloo kan jókòó lati sepade po, iyen lati mo ẹgbẹ oṣelu min in tawon yoo lo fún idibo to n bo naa.
Gbogbo awọn ara agbegbe Ogun West ni Onarebu Gbeleyi fe e loo soju lodun 2019 niluu Abuja, ta a sí gbo pe awon alatileyin e ti bere imurasile lati sagbateru e.
No comments:
Post a Comment