Aare teleri lorileede Naijiria, Oloye Olusegun Obasanjo fiwe ibanikedun ránṣẹ sí Aare ile Amerika, Donald Trump lati ki gbogbo ọmọ orileede naa kedun Aare teleri lorileede won, iyen Oloogbe George H.W Bush.
Ojo Satide Abameta to koja yi ni Aare teleri naa, George Bush jade laye leni odun merinlelaadorun (94).
Ninu atejade ti amugbalegbe Oloye Obasanjo lori oro iroyin, Ogbeni Kehinde Akinyemi fi ranṣẹ si AWIKONKO laaro onii lo ti sapejuwe Oloogbe George Bush gege bi adari rere tó fi ipa rere le'lẹ tawon adari to ku sí n wo awokọṣe e titi dasiko yi.
Obasanjo ni kii se awon ebi tabi ile Amerika nikan ni iku George Bush kan, bi ko se gbogbo agbaye, nitori naa lawon se gbogbo máa rántí é ni gbogbo ìgbà, paapaa lasiko to papoda yi.
No comments:
Post a Comment