KERESIMESI: EYI NI BI SOOSI TREASURE HOUSE OF GOD SE FI OUNJE BO EGBERUN MEJO EEYAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 25, 2018

KERESIMESI: EYI NI BI SOOSI TREASURE HOUSE OF GOD SE FI OUNJE BO EGBERUN MEJO EEYAN


Bi e se n ka iroyin yi lowo, ni inu opo awon ara ipinle Ogun ati agbegbe e si fi n dun lori bi okan lara awon soosi to fikale siluu Abeokuta se fi ounje odun keresimesi bo opo awon eeyan, bii alaini, opo atawon to ku die kaato fun.


Gege bi AWIKONKO se gbo, egberun marun eeyan lawon ti soosi naa seto lati fi ounje odun keresimesi bo, paapaa lati mu inu won dun lasiko odun yi, sugbon si iyalenu, awon ti won je anfaani naa ko din legberun mejo.


Opo awon to b'AWIKONKO soro nipa agbekale eto naa ni won n kan saara si oludasile soosi naa, Pasito Seye Senfuye atawon alakoso soosi naa fun bi won se n fi emi aanu ati ife han sawon araalu.


Be o ba gbagbe, egberun merin eeyan lawon ti soosi Treasure House of God to fikale sadugbo Agbeloba niluu Abeokuta yi fi ounje bo lodun keresimesi to koja, iyen odun 2017, nigba ti won fi ounje bo awon egberun meta lodun 2016.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI