Oludasile ẹgbẹ Odua Peoples Congress, OPC, Dokita Frederick Fasehun ti jade laye laaro oni, leni odun metalelogorin.
Agbenuso fun agba ologun tile Yoruba naa, Ogbeni Adeoye Jolaoso lo kede iku baba naa pe ile iwosan LASUTH lo dake si leyin aisan ranpe.
Aisan ojo ogbo la gbo pe o fa sababi iku baba naa, leyin ti won ti da a duro fun ojo merin, nibi to ti n gba itoju ki olojo to o de.
Ojo Tusde to koja la gbo pe won sare gbe omo bibi ilu Ondo naa lo si osibitu nigba ti asian naa wo o lara.
Ekunrere iroyin naa n bo laipe.
No comments:
Post a Comment