Okan lara awon gbajumo sorosoro ni Olumide
Awolowo, eni to mo nipa tifun-tedo ise naa, idi niyii tawon ore e fi maa n pe
ni Orobo Presenter. Sugbon laipe yii la gbo pe okunrin to tun maa n bawon kopa
ninu fiimu Yoruba gbegba oselu, o si n dije fun asoju omo ile igbimo asofin ti
ekun Abeokuta South labe egbe oselu AD ninu ibo to n bo lodun 2019.
Oniroyin wa ka okunrin to wa to di sorosoro
oloselu naa mo koro, nibi to ti ba wa so erongba e lati dije fun ipo omo ile
igbimo asofin nipinle Ogun, to si ni egbe oselu AD toun fe e gba jade setan lati gbajoba lowo ijoba APC, paapaa Gomina Ibikunle Amosun. Ohun to ba wa so niyii.
Bawo ni
Olumide Awolowo se di oloselu
Lakooko, oselu bere latinu Ile, de agbole
titi de agbegbe de ipinle ati orile- ede. Bi a ba wa n soro oselu awarawa, inu
eje lo wa, bee si ni a ko le koyan Oloogbe Jeremiah Obafemi Awolowo kere.
Sorosoro to danto mi ni mi loooto, sugbon mo n se oselu pelu e
lati bii ogun odun o le die seyin, oselu mi bere latigba ti mo ti wa nileewe
Government Technical College,
Olobe, lati odun 1997.
Nitori pe mi o ki i fee kiya je eeyan lodo
mi, mo tipase e di agbenuso fun awon akekoo nigba naa bi a se bere si wonu
oselu niyen.
Awon ohun ti
mo ni fawon eeyan mi
Mo fee fi eto ati ona iselu han awon eyan
taarata laiyo awon akegbemi paapaa seyin. Awon eto ti mo ni dara gan an, o si
to bii melo kan, awon abadofin kan wa ti a le se lati mu igbe aye iderun ba
awon mekunnu.
Iro-ni-lagbara awon ojulowo odo, abadofin
dida ileese sile loruko ijoba ipinle ti yoo mu irorun ba awon ara ilu. ilana
igbalode la o fi see.
Awon abadofin lati gbogun ti iwa ibaje ati
ijiya aito lawujo, ati beebee lo.
Idi ti mi o
fi dije labe egbe oselu Olusegun Osoba
Baba mi ninu oselu ni Oloye Olusegun Osoba,
sugbon bi mo se jiya to leyin won, ti mi o kuro lo segbe mii in yato si ibi ti
won ba wa, ti pupo awon oloselu mo mi doju amin, se ni mo le so pe won ko pe mi
si ipo tabi fun mi ni ipo kan ri, boya lati wa dupo tabi gba ipo.Mo wa pelu won
titi di igba ti eni to ri iwulo mi ra foomu idije fun mi.
Ni afikun, inu egbe AD yi ni mo ti sise
takuntakun ni odun 1998, nigba ti mo da egbe akekoo to n sise fun egbe AD sile
ta a pe ni STUDENTS ALLIANCE FOR
DEMOCRACY (S.A.D) sile, boya lati ara iwa mi, ati jije olooto eniyan ni mo fi
wa n jere re bayi leyin ogun odun.
Lakotan, nibi ti won dori oselu kodo sii loni
in, ko le faye gba iru awa ti ko ni owo to maa fi ra ipo ninu oselu pelu gbogbo
opolo ta a ni, nitori awon onisowo oselu lo po bayii ju awon to fee selu.
Egbe oselu
AD lo maa wole gomina lodun 2019
Pelu gbogbo awon odo olopolo pipe ta a ko jo
fun oselu takoko yii, ati pe oselu akoko yii ki i se egbe rara,eeyan la maa
dibo fun, latari pe egbe ti feyin wa janle, mo mo daju pe egbe AD lo maa joko
lori aga gomina nipinle Ogun ni 2019 lase Edumare nitori awon eto ati ilana
egbe AD ko lafiiwe, eyin naa saa ri ni
eto isejoba Oloye Olusegun Osoba laarin 1999- 2003, ijoba wo lo tun dabi e lati
igba naa.
Awon to n
fowo ra ibo
Hmmmm, awon ojelu to n pe ara won ni oselu ni
won n se bee, nitori ti won ti kuna lati se ohun to to ati eyi to ye lakoko. Ni
won fi n fi tipa-ti-kuu-ku du ipo oselu. Awon ni won mon on mo fi ebi pa
araalu, won a tun da ounje die sita lasiko ibo, ki awon ara ilu tun le dibo fun
won, Iwa to buruku jai ni.
Awada ko o,
mo n dije fun ile igbimo asofin nipinle Ogun
Oro awada ko ni eleyii oo, mo n dije sile
igbimo asofin tipinle Ogun lati soju Abeokuta South.
Egbe
sorosoro fun mi ni atileyin
Mo dupe gidigidi lowo awon egbe pedepede
nipinle Ogun ati ni Nigeria, nitori atileyin to gboopon ni won fun mi, Nitori
pe won mo pe mi o ki i se aladanikanje atelero tara eni nikan.
Lati ori
alaga egbe wa, Olufemi Omilani Iyanda, dori omo egbe to kere ju, won mo
pe ipo yi ki i se ti Olumide Awolowo, ipo egbe FIBAN ni.
Ki i se
gbogbo nnkan lowo o
Beeni o, owo ni keke ihinrere, sugbon gbogbo
e ko lowo. Mi o lowo sugbon mo ni eyin eyan rere lara, owo ti a gba laaye ninu
eto ikopa lati yan eeyan sipo, lo je ka a ba ara wa nibi ta a wa yii. Ohun lo
je ka maa sibodi, ohun lo faye gba awon ojelu ninu oselu ti won fi n ri eto
iselu bii okoowo lati lowo.
Gege bi e ti mo pe entertainer ni mi, a o se
eto si se awari awon ogoipinle Ogun latara ebun, ati ere idaraya fun awon tara
won pe atawon akanda eyan.
O se e se
fun wa lati gbajoba lowo Amosun
O se e se, nitori gbogbo araalu atawon
oloselu ti mo pe egbe APC nipinle Ogun ko se daradara to, imo tara eni nikan
ati adanikan je ni asole egbe won fi ba irinajo egbe naa je.
Mo nigbagbo
ninu ajo INEC
Beeni mo nigbagbo ninu ajo INEC. Mo si mo pe
won ko ni se ohun ti ko to, mo si tun gbadura pe Olorun yoo ran ajo naa lowo
lati ko ogo eto idibo to n bo ni 2019 ja.
No comments:
Post a Comment