AWON TO LU ILEESE OBASANJO NI JIBITI TI FOJU BALE EJO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 19, 2018

AWON TO LU ILEESE OBASANJO NI JIBITI TI FOJU BALE EJO

Kani awon ore mejo kan ti won fesun jibiti kan mo pe asiri awon maa pada tu sawon olopaa lowo, depodepo wi pe awon yoo foju bale ejo ni, o see se ki won ma ti e pinu lati ja ole owo to to milionu metadinlogorin (77m) naira ti wom tori e foju won bale ejo lojo Fraide ose to koja yi niluu Abeokuta.


Bo tile je pe awon yooku ti won fesun kan ti na papa bora, sugbon Yusuf Azeez, omodun metadinlogbon (27); Olaosu Dauda, omodun merindinlogoji (36); Olufunmi Falade, omodun merindinlogoji (36); Olatunbosun Ogunseye, omodun mejidinlogoji (38); Samson Onabanjo, omodun marundinlogoji (35); Abiodun Alonge, omodun marundinlogoji (35); Moyindun Green, omodun metalelogun (23) ati Busura Habib, toun je omodun merinlelogun (24) lawon ti won foju won bale ejo.

Oteeli Aare teleri lorileede yi, Oloye Olusegun Obasanjo, iyen Green Legacy Resort to wa lagbegbe Oke-Mosan niluu Abeokuta lawon eeyan naa ti n sise, ta a si gbo pe gbogbo won gbimo po lati lu jibiti owo ti won fesun e kan won yi.

Nigba to n fesun naa kan won nile ejo, Ogbeni Bukola Abolade to je agbejoro fawon olopaa so pe laarin osu kinni si osu kejo odun yii lawon eeyan naa fi ji owo yi ko, nitori pe diedie ni won n ko o salo.

Abolade ni iwa ti won hu naa tako ofin iwa odaran tipinle Ogun todun 2006, idi ni yii tawon fi ko won wa sile ejo lati gba idajo to to si won.

Ninu awijare awon ti won fesun kan yi ni won ti lawon ko jebi pelu alaye, sugbon adajo ile ejo naa, Titilayo Bello so pe ki won si toju alaye won.

Bello ni bo tile je pe won jebi looto, sibe oun yoo foju aanu wo won pelu beeli, nitori naa ki eni kookan won san milionu meji naira gege bi owo beeli pelu oniduro meji otooto ti won n san owo ori won deede, ti won si tun ni dukia ti won yoo fi duro.

O wa a pase pe ojo kejo osu kinni on odun 2019 ni igbejo min in yoo tun waye, sugbon titi ta a fi sakojopo iroyin yi tan lawon mejo naa ko tii ri oniduro funra won, tesan olopaa ni won si wa ti won n gbategun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI