AWON AKORIN SOOSI MFM GBA AWOODU BBC LAGBAYE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, December 1, 2018

AWON AKORIN SOOSI MFM GBA AWOODU BBC LAGBAYE


Wọn ni iṣẹ ti ẹda ba mọn ọn ṣe laye, ko tẹra mọn ọn, iyẹn to ba fẹ ẹ gba iyi, ogo ati ọla nidi ẹ, paapaa bo ba fẹ ki aye maa kan saara soun ni gbogbo igba. Eni ti aye ba si yẹ, eni to ba yẹ ka gbe ọla ati iyi fun naa ni n gba a.

Wọnyi lọrọ to lọ nibamu pelu bi awọn akọrin ti ṣọọṣi Ori Oke Ina ati Iṣẹ Iyanu (Mountain of Fire and Miracles Ministries), MFM ṣe gba awọọdu gẹgẹ bi ẹgbẹ akọrin to daraju lọ lagbaye, eyi ti ileese Britich Broadcasting Commission, BBC ṣagbekalẹ ẹ laipẹ yi, to si wa s'opin lọjọ Sande to kọja, iyẹn ọjọ karundinlọgbọn oṣu kọkanla to kọja yi lorileede United Kingdom.

Ọpọlọpọ awọn ẹgbẹ akọrin la gbọ pe wọn kopa nibi idije naa, sugbon to je pe awọn ẹgbẹ akọrin marun ni wọn pada wọ ipele aṣekagba.

Fawọn ti ko ba mọ, Oludasilẹ ṣọọṣi MFM lagbaye, Dọkita Daniel Kọlawole Olukọya jẹ ọkan pataki lara awọn Pasitọ ti kii f'ọwọ yẹpẹrẹ mu orin kikọ, paapaa ẹka ẹgbẹ akọrin ti ṣọọṣi e, ko da, to ti ni oriṣiriṣi akaikatan orin to ti ko jade, tawọn orin naa si jẹ eyi tawọn eeyan ko le ṣe ki wọn ma ko lojumọ.


Ko si ọmọ ta a bi sinu ṣọọṣi MFM lonii, ti ko ni i mọ nipa orin, tabi bi wọn ṣe n lo awọn ohun-elo orin, lati ori duuru, tabi eyikeyi ninu awọn nnkan to n gbe orin jade, lati kekere si ni wọn ti n kọ wọn lai gba owo lọwọ wọn.

Idi ẹ pataki gan an re e tawọn ẹgbẹ akọrin ṣọọṣi fi n tayọ laarin awọn akẹgbẹ wọn kaakiri agbaye.

Ninu ṣọọṣi MFM lagbaye, paapaa ẹka ẹgbẹ akọrin, titi lailai ni wọn yoo fi maa ranti ọjọ karundinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2018, to jẹ ọjọ ti ileeṣe BBC gbe awọọdu nla rabandẹ fun ẹgbẹ akọrin Shalom Chorale ti orileede UK lati gbe oriyin fun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe.

Ileeṣe BBC la gbọ pe wọn ṣagbekalẹ eto ọlọdọọdun kan fawọn akọrin igbagbọ lagbaye, eyi ti wọn pe ni BBC SONGS OF PRAISE GOSPEL CHOIR.

Kii ṣe pe orileede UK nikan ni wọn ti mọ nipa eto yi, kaakiri agbaye lawọn eeyan ti mọn ọn, to si jẹ pe ọpọ awọn eeyan ni wọn kii fẹ ẹ ki eto naa fo wọn ru lai wo o.

Ninu ọrọ Oludasilẹ ṣọọṣi MFM, Dọkita Daniel Kọlawole Olukọya lo ti gboriyin fawọn akọrin naa, to si ṣeleri fun wọn pe oun yoo tubọ maa ṣe iranwọ fun wọn ni gbogbo igba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI