Pelu bi nnkan se n lo yi, afi ki ijoba, paapaa ileeṣẹ olopaa tubọ tẹra mọ gbigbogun ti iwa ibajẹ, paapaa ìwà òdaran lawujo pẹlu bi odun se n sunmọ yi.
Láì pe yi ni asiri gbajumo onileese nla kan, Ṣupọ Bamidele tu s'awọn olopaa ipinle Osun lowo, nigba ti won ni won ba eya ara eeyan lọwọ e, to sì ni oku ti won ṣẹṣẹ sin in loun lòó hu.
Agbegbe Ifon niluu Ile-Ife nipinle naa la gbo pe awon eeyan ti fura si Ṣupọ pẹlu baagi to gbe dani, paapaa bi won se lo n run pa awon araalu.
Oorun naa tawon eeyan ko le gba mọra mọ lo je ki won loo da Ṣupọ duro lati ye nnkan to wa ninu baagi ọwọ e wo, iyalenu lo je nigba ti won ba ori eeyan, ẹran ara eeyan ati ọwọ meji nibe.
Lesekese lawon eeyan ti pe le e lori lati luu, ati pe opelope awon eleyinju aanu ti won f'oro naa to awon olopaa leti, ko too di pe won tuu sile, bi kii ba a ṣe bẹ, won ki ba ti luu pa, ki won sì tún dana sun un.
Nigba ti Ṣupọ n jewo fawon olopaa, ọ ni babalawo oun toruko e n je Amos Suleiman lo ran oun nise naa, oogun owo lo si fe e fi se foun.
Idi ni yii to loun fi gba mosuari lo lati loo hu oku jade, to sì pin eya ara e si wẹwẹ lati loo gbe e fun Amos, ki owo palaba é to o segi.
Nigba ti won loo gbe Suleiman nile e, nnkan to so ni pe iro ni Ṣupọ pa moun nitori toun ko ran an nise kankan, ati pe awọn ko jọ ladehun kankan, nitori naa ki won mu daadaa.
Komisana olopaa ipinle naa, Fimihan Adeoye ti so pe dandan ni kawon mejeeji jiya ese won labẹ ofin, nitori naa, ki iwadi tubọ tẹsiwaju ki wọn too foju bale ejo.
No comments:
Post a Comment