ABEL, OMO NAIJIRIA TO LU OBINRIN NI JIBITI NI INDIA DERO EWON - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 4, 2018

ABEL, OMO NAIJIRIA TO LU OBINRIN NI JIBITI NI INDIA DERO EWON

Kani baale ile eni ogbon odun, Abel Odera mo pe asiri oun yoo pada tu, o ṣee ṣe kó ti tete wa woroko fi sada, ati pe afaimo ko ma je pe kirikiri lorileede Naijiria ni Abel to filuu India sebugbe yoo ti sodun yi.

Ohun ta a gbo ni pe ori ero ayelujara ni Abel, omo bibi Naijiria ti lu obinrin omo ile India kan ni jibiti owo to po repete, pẹlu etanje lati fẹ obinrin naa.

Oruko ti won ni Abel n lo fi lù jibiti ni Dokita Ayush Tyagi, nibi to ti ba obinrin naa pade, gbara ti won sì pàdé lo ti bere sii pa iro orisirisi fún ùn pe oun padanu iyawo oun sinu ijamba moto, idi ni yii toun fi n gbe pelu omo oun.

Ko pe ti won pade la gbo pe obinrin naa ti fi owo ranṣẹ sí Abel pe kó máa bo ni India, iyen lodun 2014. Inu osu kejo odun yi la gbo pe enikan pe obinrin kan to pe ara e ni oṣiṣẹ irina pe e lori foonu pe awon ti mu Ayush sile, nitori naa, ayafi to bá san owo kawon yóò fi silẹ.

Lesekese la gbo pe obinrin yi ti lòó wa owo, to sì fi ranṣẹ síi. Latigba towo naa ti tẹ Abel lowo ni ko ti fe e ba olólufe e lori ero ayelujara yi soro mo, idi ni yii tiyen fi lòó f'oro naa to awon olopaa leti.

Ojo Fraide to koja, iyen ogbon ojo osu kọkànlá to koja yi lowo palaba Abel segi, to sì ti n ka boroboro latigba naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI