WON JU OMO NAIJIRIA SEWON ODUN META L'AMERIKA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 2, 2018

WON JU OMO NAIJIRIA SEWON ODUN META L'AMERIKA

Lojo Tusde to koja yi nile ejo kan nile Amerika ju ọmọ Naijiria, Clement Onuama sewon odun meta ati osu merin pere latari awon esun jibiti orisirisi ti won fi kan an.


Egberun lona egberun mílíọ̀nù dola la gbo pe Clement atawon ore e kan ti lù awon èèyàn ni jibiti lati ori ẹrọ ayelujara, sugbon t'asiri won pada tu sita.

Lojo kejidinlogun osu kewaa ni Adajo Judge Conley ti koko ju Orefo Okeke toun ati Clement jo n sise jibiti yi sewon osu marundinlaadota (45), ti won sì pase ko da mílíọ̀nù mefa din diẹ owo dola (582,955.90) pada.

Agbegbe kan nitosi Arlington, Texas la gbo pe Clement ni ileese sí, ileese naa to n ri soro moto tita ati titunṣe, ọ sí ti lo ogbon jibiti lati fi gba awọn èèyàn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI