WON FORUKO SENETO IPINLE OSUN LU AWON EEYAN NI JIBITI LORI FACEBOOK - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, November 4, 2018

WON FORUKO SENETO IPINLE OSUN LU AWON EEYAN NI JIBITI LORI FACEBOOK

Asofin to n soju awon eeyan Ife/Ijesa nile igbimo asofin agba orileede yii, Seneto Babajide Omoworaare ti ke si gbogbo awon ololufe re lati sora fun awon onijibiti ti won fi oruko re si ayederu itakun feesibuuku laipe yii.


Omoworaare, ninu atejade kan ti akowe iroyin re, Tunde Dairo fi sita so pe oun ko mo si itakun feesibuuku eleyii ti awon gbajue naa fi n beere owo idupe tabi owo imoore fun awon ise ijoba ti won gbe sibe.

O ni igbese ti bere pelu awon agbofinro lati rii pe owo te awon eeyan ohun ki won le foju winna ofin fun igbese ti won gbe naa.


Omoworaare waa kilo fun awon ololufe re pelu awon eeyan agbegbe to n soju lati mase ni nnkan kan se pelu enikeni to ba n beere owo lọwọ wọn fun iranwọ kan tabi omiin lorukọ oun nitori oun ko ran enikeni nise rara.

O fi kun ọrọ re pe ki ẹni to ba daṣẹ pọ pelu awon onijibiti naa mọ pe ko si nnkan to kan oun ninu ẹ rara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI