Abenugon ile igbimo asofin ipinle Ondo ti won dibo yo nipo, Onorebu David Oleyeloogun ti sọ pé kò sí nnkan to jo o wí pé wọn yo oun kuro nipo naa, ati pe eremode lasan láwọn to n gbe iroyin kaakiri n se.
Bẹẹ lọ so pe igbakeji oun naa, Onorebu Iroju Ogundeji ti won tun so pe won yo nipo naa, iro lasan to jinna sí òtítọ ni, ati pe awon mejeeji sì ni ojulowo olori ati igbakeji ile igbimo asofin ipinle naa.
Ojo Fraide to koja yi ni Oleyeloogun soro yi lasiko to n bawon akoroyin ipinle naa soro nile igbimo asofin naa to wa niluu Akure.
O so pe leyin tawon mejidinlogun ninu awọn merindinlogbon ti won bu owo lù iwe ti won fi n béèrè fún pe ki won yo awon nipo, o ni nnkan se naa kii se pe won yo awon nipo, nitori pe won ko gbe korọọmu kalẹ.
Ninu oro e siwaju sii, "Emi sì ni olori ile igbimo asofin ipinle Ondo yi; Onorebu Iroju Ogundeji náà sì ni igbakeji mi. Kò sí nnkan to ye, mo fi n da a yin loju.
O so pe kò sí nnkan meji to n fa gbogbo laasigbo yi bi ko se ti wahala to n sele laarin awon asoju-sofin, toun sí nigbagbo pe yóò niyanju lai pe.
Saaju akoko yi ni alaga igbimo lori ọrọ iroyin, iyen House Committee on Information, Ogbeni Fatai Olotu so pe nnkan to n fa wahala naa ko seyin esun iwa ibaje ti won fi kan awon mejeeji.
Wọn sì ti yan Ogbeni Olajide George lesekese gege bi olori ile igbimo asofin naa, ti won tun yan Abimbola Fajolu gege bi igbakeji.