Ojule kesan an, adugbo
Oyetayo Olafisoye ni Badore, lagbegbe
Westwood Estate niluu Ajah ni won so pe okunrin naa n gbe.
Gege ba a se gbo, Ojo
Abameta Satide to koja yii lowo awon olopaa ti te e, ti won si ti mu un si
tesan won niluu Langbasa lagbegbe naa.
Ninu oro oga agba ni
tesan olopaa ohun, Arabinrin Ada Okafor (SP) lo ti so pe, “Iwadii wa fi han wi
pe nise ni okunrin yii ba omo e, omo odun meji sun titi to fi ko aisan buruku
ran an.”
Ninu oro alukoro fun
ileese olopaa, Chike Oti, (CSP) ni tie lo ti so pe “Nigba ti okan lara awon
olopaa ti won je obinrin beere lowo omo naa wi pe ta lo ba se iru ere buruku
bee, nise lo nawo si baba e, to si tun juwe orisirisi ara mi-in ti okunrin naa
fi da lasiko to n fipa ba a lopo.”
O ni komisanna olopaa,
Imohimi Edgal ti pase wi pe ki won gbe igbese iwadii gidi lori oro ohun, bakan
naa lo ti wa ro awon obi ati alagbato lati maa mojuto awon omo won daadaa,
nitori pe pupo ninu awon irufe onise ibi ohun ni won gba igboro kan bayii.
LATI: MAGASINNI ALORE