Seneto Buruji Kasamu to n soju ekun Ogun East, Mr
Buruji Kashamu niluu Abuja ti gba alaga egbe oselu PDP lapapo, Ogbeni Uche Secondus lamoran pe ko tete wa nnkan se si oro igun ti egbe naa ni nipinle Ogun, paapaa lati le je ki alaafia joba ninu egbe naa, dipo ko maa fa ori apa kan da apa kan si.
Kasamu ni ajo eleto idibo, iyen INEC ti so pe oruko awon adije ti isakoso Adebayo Dayo fi ranse si won lawon mo gege bi ojulowo, dipo eyi ti igbimo amusese fi ranse si won.