Aaro onii ni Odunlade gbe foto iyawo é sori ikanni eka ayelujara, Instagram lati fi ba iyawo é yo, tawon eeyan naa sí ti bere síi kíi latigba naa titi dasiko yi.
Ohun tawon kan n so ni pe Odunlade Adekola ko se iru nnkan bayii ri, idi ni yi to fi je pe opo awon ti ko mo iyawo é fi máa n gbé awọn iroyin ti ko je òtítọ nípa gbajumo osere taye n gba ti lasiko yi jade bo se wù wọn, paapaa nipa ọrọ igbeyawo e.
Ohun tí Odunlade ko sori Instagram naa ni pe "Ojo ibi le wa, ko sí lo, ife mi ati ibọwọ ti mo ní fún é kò níí pare. Ku ayeye ojo ibi ololufe mi!"
Awon tó ri nnkan ti Odunlade se yi ni won n so pe se lo fi ìfẹ hàn siyawo é, bi eni to n se ikomo ọmọ ọjọ mẹjọ.
No comments:
Post a Comment