Ọgbẹni Aregbesola lo soro naa lonii ojo Satide Abameta lori telifisan ati redio niluu Osogbo, eyi to pe ni 'Ogbeni Till Day Break', eto naa to fi faaye sile fawon oniroyin atawon araalu lati beere orisirisi ibeere nipa ijoba e lowo e.
Nibe lo ti so pe oun ko gba owo osu laarin awọn asiko toun fi wa nijoba gege bi gomina.
Yato si, Ogbeni Rauf Aregbesola tun je kó di mimo pe oun ko ni apo ile ifowopamo sí kankan, debi pe oun yoo ni owo nipamo, paapaa niwon igba to je pe ijoba ti pese gbogbo awọn nnkan toun yoo lo lati fi gbe igbe aiye irorun gege bi olori.
Ninu oro e, Aregbesola so pe "Mi o tíì gba owo osu kankan latigba ti mo ti di gomina ipinle yi. Ipinle yi lo n bọ mi, awọn ni wọn n ra bentiroolu sinu mọto mi, ti wọn tun pese ile fun mi ti mo n gbe.
"Pẹlu gbogbo awọn nnkan wọnyii, mi o nilo owo kankan, nitori pe ko sí nnkan ti mo tun fe e fi owo ṣe.
"Mi o lowo kankan, bẹẹ ni mi o ni apo owo nile ifowopamo níbikíbi. Mi o nile min in yatọ si eyi ti mo ti ko ki n to o di gomina. Ẹnikẹni lo le jade loo sewadi lati mo boya mo ni apo owo nile ifowopamo."
Bẹ o ba gbagbe, ojo ketadinlogbon osu yii ni Gomina Rauf Aregbesola yoo gbe ijoba sile fun eni to jawe olubori nibi idibo gomina nipinle naa ti won di koja lo, iyen Alaaji Gboyega Oyetola.
Bakan naa ni Aregbesola tun sọ ọ sita pe ojo Monde to n bo yi, iyen ojo kokandinlogun osu yi loun yoo ko gbogbo ẹru oun kuro nile ijoba ipinle naa toun n gbe, lati fun Alaaji Oyetola laaye lati ṣe awọn atunṣe to ba yẹ fun itelorun e.
No comments:
Post a Comment