Ogbontarigi
ojise Olorun ti Olorun n gba owo sise ara, aami ati ise iyanu lorileede
Naijiria, paapaa ninu soosi The Blessed New Jerusalem ni Alagba Samuel Awolude
(JP). Awon ipa ti Alagba Awolude si ti ko ninu ise Oluwa ko se e fenu ka tan,
awon to ba mon on lo mon. Odu si ni Alagba yi, kii sai mo f’oloko. Awon ipa to
si ti ko lagboole igbagbo ti je ko gba opolopo awoodu lodo ijoba, nileese
aladani ati laarin ilu, to fi mo awon egbe lorosirisi. Ojo Satide to n bo yi,
iyen ojo kewaa osu yi ni soosi naa tun fe e fi oye tuntun da a l’ola, iyen oye
His Emminece, Most Reverend Apostle. Alagba Awolude b’AWIKONKO soro lai pe nipa
irin ajo aye, paapaa irin ajo e sidi ise Oluwa. Eyi lawon ohun ti iranse Olorun
naa ba Olootu AWIKONKO, 'Segun Okeowo so.
AWIKONKO:
E JE KA MO YIN LEKUNRERE?
AWOLUDE: Emi
ni His Eminence, Most Rev. Apostle Samuel Oladele Olorunsogo Awolude, soosi The
Blessed New Jerusalem Church of Christ Nigeria, to wa lopopona Kuto niluu
Abeokuta. A bi mi lojo kokanla osu kejo odun 1952 si idile Emmanuel Sotayo
Awolude ni abule Baase, nijoba ibile Owode, ipinle Ogun. Ileewe Zion African
Church ni mo ti bere. Leyin ti mo pari ileewe mo lo sileewe onimo-ero
(engineering) niluu Abeokuta. 1965 ni mo jade ileeko alakoobere, Leyin ti mo kuro nibe, mo lo
kekoo nipa imo-ero niluu Abeokuta ti mo si kekoo gboye e lodun 1971. Igba ti mo
kuro nibe ni mo loo sise nileese Marchant kan niluu Eko. Igba ti mo kuro nibe
ni mo pada wa siluu Abeokuta ti mo fi wa a da ise temi sile, nibi ti mo ti n
soowo moto. Mo tun lo si ileeko kan, igba ti mo de ni mo bere sii ra moto fawon
eeyan, ti won n san owo e diedie. Enu ise naa ni mo wa ti mo fi feyawo mi, ti
Olorun si jogun awon omo rere fun wa. Gbogbo awon omo mi ni Olorun bukun fun.
AWIKONKO:
IGBA WO GAN AN LE EREE ISE OLUWA ATI PE BAWO LE SE BERE?
AWOLUDE: Ta a ba ni
ka wo o, ojo ti won ti bi mi lodo Baba Oloruntedo Solomon nijoa ibile Owode ni
asotele ti jade pe ise Oluwa ni ma a se. Mi o tete fokan sii, gbogbo bi mo se n
lo kaakiri, ti mo tun da ileese mi sile ni Olorun n fara han mi pe ki n wa sise
foun. O ti le laadota ti mo ti wa lodo Baba Peter ti won je Baba mi ninu Oluwa,
ibe ni mo ti bere ise Oluwa lati Burooda, Diakoni, Pasito, Efanjeliisi,
Refurendi, Apositeli, Apositeli Agba, titi ti mo fi di Apositeli Ololajulo
Agba, iyen His Eminence, Most Senior Apostle.
AWIKONKO:
LAARIN ASIKO TI WON N PE YIN FUN ISE OLUWA, NJE E TI E F’IGBA KAN SA SEYIN?
AWOLUDE: Beeni, mo
sa seyin, mo ti e sa jinna nigba ti won n so fun mi pe mo maa sise f’Oluwa, ti
Olorun fun’ra e tun n fi iran han mi, nitori ti mo wo o pe bawo ni maa se fi
gbogbo nnkan ti mo ni sile loo sise Oluwa, tani yoo maa ba mi mojuto gbogbo
nnkan ti mo ni. Emi to je pe won n ko owo wa fun, ti mo n ra moto, ti mo n tun
un ta, nibo ni mo ti fe e rowo jeun, ti maa tun maa fi dawon eeyan l’ekoo,
sugbon nigba to to asiko lodun 1972, ni Olorun sese wa a fi owo agbara e mu mi
pelu aisan nla kan. Aisan yen lo tun gbe mi pada sodo Baba Peter Aladura,
nitori pe mo ti na owo repete lori aisan naa, I mo se n lo si osibitu kan, ni
mo tun n lo sibomin in, won ni ki n wa ra eran fi rubo, ki n setutu, mo si so
fun won pe mi o le se e, idi ni yii ti mo fi lo sodo Baba Peter nibi ti Olorun
ti gba ra emi mi pada. Igba to si je pe odo Jesu ni mo ti ri iwosan, lo je ki n
kuku fi gbogbo aye mi fun Jesu Kristi. Odun 1999 ni mo gba ise Olorun
tokan-tokan, mo si di iranse Olorun soosi Blessed New Jerusalem Church, to wa
niluu Abeokuta.
AWIKONKO:
GEGE BI ENI TO N ROWO TELE NIDI ISE TI E DA SILE, KO TOO DI PE E GBA ISE OLUWA.
LAARIN IGBA TI E BERE ISE OLUWA, NJE E FIGBA KAN RI RO O PE E FEE FI SILE?
AWOLUDE: Mo ti ro o
ri, nitori pe laarin igba ti mo n sise Oluwa yi ni mo loo sise nileese eto
ikansira-eni to je tijoba apapo, ileese naa lo di NIPOST lonii. Igba kan wa ti
isoro de, ti ko si owo mo, gbogbo igba yen, ko rorun rara nitori pe bi eeyan ba
n sise Oluwa nigba min in, o tun nilo owo ninu, sugon pelu ifarada, mo fori
tii, Olorun si gba ogo. Mo ro o laarin igba ti adojuko de pe mo fe e kuro nidi
ise Oluwa, sugbon sibe, emi Olorun ran mi lowo.
AWIKONKO:
AWON IBO NI ISE OLORUN TI GBE E YIN DE?
AWOLUDE: Lati sise
Oluwa ko rorun, laarin igba ti mo da ise sile, ti mo n ra moto fawon eeyan,
temi naa tun n ta a, oju kan soso ni mo wa. Sugbon leyin igba ti mo gba ise
Oluwa, awon ibi ti mi o lero pe mo le de ni mo ti lo lati ara ise iranse yi.
Leyin ti mo di iranse Olorun ni mo lo si Israel, Jerusalem, Turkey, Palestine,
USA atawon orileede min in.
AWIKONKO:
IHA WO LAWON EBI YIN KO SI NIGBA TI E GBA ISE OLUWA, PAAPAA NIGBA TI NKAN KO FE
E FI BE E JO ARA WON MO?
AWOLUDE: Gbogbo igba
yen, kii se pe o le to ki n lo maa toro je, sugbon awon ebi mi farad a, paapaa
iyawo mi, o fowosowopo pelu mi, o si gba ruku ti mi, o duro ti mi.
AWIKONKO:
NJE E TI E LE SO DIE FUN WA NIPA ITAN SOOSI THE BLESSED NEW JERUSALEM ATI PE
AWON IBO NI EKA SOOSI YI TI TAN DE?
AWOLUDE: E seun!
Adugbo kan ti won n pe ni Oke-Itoku niluu Aeokuta lo ti bere lodo Baba Peter ti
won je Baba mi ninu Oluwa ni nnkan bi 1970, ibe la ti kuro lo si Kuto ta a wa lonii.
A ko si labe soosi kankan nitori pe se la da duro ta a si foruko sile lodo
ijoba apapo. Ko si wahala kankan ninu soosi yi. Kaakiri orileede Naijiria la wa
lonii. A ni eka kaakiri agbaye.
AWIKONKO: AYEYE
IDANILOLA NKAN BO LOPIN OSE YI NINU SOOSI YIN, KI LE FE E SO NIPA E?
AWOLUDE: Mo ni lati
dupe lowo Olorun fun ayeye naa nitori pe oore-ofe Olorun ni, kii se agbara mi
tabi ogbon ori mi. Mo tun ni lati dupe lowo awon ti won duro ti mi paapaa awon
igbimo agbaagba soosi yi fun ifowosowopo won pelu mi. Won fe e fi mi je Most
Senior Apostle, . Igbimo agba kii deede fi ipo daayan l’ola, iwa ni won maa n
wo, ebun eeeyan ninu agbara Emi Mimo, akitiyan ninu ise Oluwa.
AWIKONKO: KINNI
IYATO TO WA LAARIN ENI TO PE ARA E ATI ENI TI OLORUN PE?
AWOLUDE: Odara ki
Olorun pe eeyan fun ise ju keeyan loun fi ara e sile fun ise Olorun lo. Bi
Olorun ko ba pe eeyan, nnkan to ba wu eni na ni yoo maa se e. Ebi lo le opo
awon de ibi ise Oluwa, nigba ti Olorun ma ape mi, mo ti nise mi lowo, ti mo tun
da ileese mi sile, mo sa seyin, sugbon Olorun pada fi owo agbara e mu mi. Bi
Olorun ba peeyan, o maa pese awon nnkan irorun fun un, awon nnkan to ma maa je,
o si maa pese ona abayo pelu ibukun.
AWIKONKO:
KINNI ORO YIN FAWON TO N BO SIBI AYEYE NAA?
AWOLUDE: Adura ni mo
kan fe e gba fun won pe Olorun a pa alo ati aabo won mo. Kaakiri Naijiria to fi
mo oke-okun lawon eeyan ti n bo wa a ye mi si. Gbogbo won ko nii kabamo.
AWIKONKO:
AWOMRAN YIN FAWON TO FE E SISE OLORUN
AWOLUDE: Eni ti
Olorun ba pe lo n yan, eni to a si yan lo n da l’ola, bi Olorun ba peeyan, ti
Olorun ko pe maa n ni wahala to po. Looto a ni lati fi ara wa jin fun ise
Olorun, sugbon ka duro de asiko ti yoo pe wa. Job 22:21 fidi e mule.
AWIKONKO: IDIBO
ODUN 2019 TO N BO LONA, KI LORO AMORAN YIN FAWON OMO NAIJIRIA?
AWOLUDE: Mi o ni amoran pupo bi ko se pe ki onikaluku
loo gba kaadi idibo alalope, iyen PVC won, ki won si dibo fun eni ti okan won ba
yan. Eni ti Olorun ba si yan, ka fi adura ran an lowo lati se aseyori. Ebe ni
mo n be pe kenikeni ma ta ibo rara, ki omo Naijiria ma se ta ibo e fun oloselu kankan, nitori pebi eni to ta ojo iwaju e ni.