Eyi ni lati fi to gbogbo awon eeyan, paapaa
awon ololufe e iwe iroyin AWIKONKO leti pe kii se iwe iroyin wa ni Oloye
Olusegun Obasanjo pe l’ejo o, enikan ti a jo n lo oruko ni Aare teleri lorileede yi
pe l’ejo latari oro to gbe sori ero ayelujara e.
Lai pe yi ni Ogbeni kan to n pe ara e ni ‘Akanda
Oro Awikonko’, eni ti won pe ni oniroyin ati sorosoro, to maa n gbe orisirisi
oro lati tabuku ijoba tabi awon eeyan sita, iyen lori redio e to n se lori ero
ayelujara gbe oro jade sita pe Oloye Olusegun Obasanjo lowo ninu awon to pa
Oloogbe Bola Ige to je gbajumo agbejoro nigba aye e.
Ohun ti okunrin ti enikeni ko tii mo d’asiko
yi so ni pe Oloye Olusegun Obasanjo lo je igi leyin ogba fawon to pa Bola Ige.
Looto, opo awon to n je AWIKONKO po lorileede
Naijiria, paapaa nile Yoruba, sugbon ileese ti wa kii se ileese tawon eeyan ko mo awon oniroyin e,
paapaa awon oludari e, Ileese wa foruko sile lodo ajo to n foruko sile, iyen
Corporate Affairs Commission (CAC) lorileede yi.
Oloye Obasanjo lo fesun kan okunrin to pe ara
re ni Akanda Oro Awikonko pe o gbe ayederu
iroyin sori ero ayelujara lati fi ba oun loruko je kaakiri agbaye, idi ni
yii ti agbejoro Baba Obasanjo fi n beere fun owo ti ko din ni bilionu kan
naira, gege bi owo itanran ati ibaniloruko je.
Ileese AWIKONKO MEDIA CHANNEL (RC: 2745139) lo n gbe IROYIN AWIKONKO jade, awa kii sii se redio ori ero
ayelujara, bi ko se nipa kiko iroyin nikan la wa fun.
Awa kii gbe ayederu iroyin jade sita, opo
awon ololufe e wa ti won n ka iroyin wa, ni won n kan saara si wa. Fun
idi eyi, paapaa awon to ti n pe wa lori foonu lotun-losi lati beere pe ki lo pa
awa ati Oloye Obasanjo po, kii se awa ni Oloye Obasanjo pe lejo.
Fun alaye lati mo eni ti Obasanjo gbe lo si
kootu, e loo sewadi okunrin naa lori www.akandaoroawikonko.com.ng.