KENNEDY POKUNSO SINU SOOSI LEYIN TO FIPA BA OMO KEKERE SUN TAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 14, 2018

KENNEDY POKUNSO SINU SOOSI LEYIN TO FIPA BA OMO KEKERE SUN TAN

Titi di bi e ti n ka iroyin yi loro odomokunrin kan, Kennedy Malikita ti won loo pokunso sinu si n je fawon eeyan, paapaa awon omo soosi naa.

 

Ojo Monde to koja yi la gbo pe Kennedy gba soosi kan ti won pe St. Peter’s Anglican Cathedral to wa lagbegbe Likoma Island lorileede Malawi lo, to si loo gbemi ara e sibe.

Ohun ta a gbo ni pe okan lara awon omo soosi naa, Ogbeni Charles lo lo si soosi naa losan ojo Monde ojo kejila osu yi lati loo gbadura, nigba to si maa wole, ko fe e le gba nnkan toju e ri gbo nigba to ri odomokunrin yi to n mi jolon-jolo loke aja to so ara e ko sii.

Idi ni yii o fi pariwo sita fawon araadugbo ti soosi naa wa. Ka to seju pe, awon eero ti peju sibe, tonikaluku si bere sii so nnkan toju won ko to, ati eyi toju won to.

 

Awon kan to wa nitosi ni won loo foro isele kayeefi naa to awon olopaa Likoma leti. Nigba ti won gbe oku naa bole, ni won sakiyesi pe awon kan sese wa a fi ojo odomokunrin naa sun lodo awon ni.

Agbenuso fawon olopaa, Mcliff Ngulube so pe Kennedy Malikita je omo abule Chamba to wa labe akoso Mkumpha ni Island. Oun naa lo je ko ye wa pe won gbe ejo Kennedy wa sodo awon pe o fipa omo kekere kan sun, tawon si ti bere iwadii lori e.

PÍN-IN KÁÀKIRI