Igbakeji Aare orileede yui, Ojogbon Yemi Osinbajo tun ti tu perepeere oro jade sita lonii Monde pe isakoso Aare ana, iyen Dokita Goodluck Ebele Jonathan lo ko orileede yi sinu oko gbese nla, eyi to fe e je isoro ti Aare Muhamamdu Buhari n dojuko.
O ni isakoso Goodluck Jonathan kun fun opolopo iwa ajebanu ati talo fe e mu mi, eyi ti ko boju mu rara.
Osinbajo ni iyanlenu lo je foun ljo kan nigba toun rii pe aadorin bilionu ni won wo jade kuro nile ifowopamo agba, iyen CB lojo kan soso, lai je pe won fi se ise akanse, ti ko si seni to soro nipa e.