GBAJUMO ONIROYIN DI APOSTELI SOOSI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, November 4, 2018

GBAJUMO ONIROYIN DI APOSTELI SOOSI

Bi e se n ka iroyin yi, inu idunnu ati ayo lawon molebi gbajumo oniroyin kan, Ogbeni Johnson Akinpelu ti ileese iwe iroyin Alaroye wa, latari bi won se so okunrin naa di Special Apostle ninu soosi alaso funfun, The Sacred Cherubim and Seraphim Church of Nigeria, Ebenezer Parish to wa lagbegbe Abiola-Way niluu Abeokuta.
 

Ana tii se Satide Abameta, ni won sayeye ifinijoye naa, ti gbogbo awon oniroyin nipinle Ogun si ti bere sii fi atejise orisirisi ranse si gbajumo oniroyin naa lati ba a yo.


Ogbontarigi ni Johnson Akinpelu ninu soosi Kerubu ati Serafu, o si ti ko ipa ribiribi lati je ki ise Olorun tesiwaju ninu soosi naa, paapaa awon eka e to wa kaakiri ipinle Ogun.


Nigba to n soro, Baba Alakoso soosi naa, Alagba Oluwasegun Sonde ti Alagba Olagoke soju e lati soro ni kii se pe won dee de fun Johnson Akinpelu  ni oye tuntun naa, bi ko se pe awon ipa to ti ko ninu soosi yi lo fa a ti won fi yan an.


Alagba Olagoke so pe looto, inu osu kinni odoodun ni won maa n se awon eto ifinijoye yi, to si je pe pupo lo ti n foju sona si osu kinni odun to n bo, iyen 2019, sugbon latari awon ayipada to waye lo je ki won pinu lati mu ojo keta osu kokanla odun yi, idi ni yii ti won fi se e lonii.


Alagba Olabinke to ta ororo le won lori ninu oro e lo ti gboriyin fun Johnson Akinpelu atawon ti won jo fun won ni oye tuntun fun ise takuntakun ti won n se, to sit un gba won nimonran pe ki won ma se je ki ise Oluwa dawo duro ninu aye won.


Nigba toun naa n soro, Alagba Johnson dupe lowo Olorun fun òye tuntun naa, bee lo tun dupe lowo awon agbaagba soosi naa.

Eyi ni die lara awon foto ayeye eto ayeye naa bo se lo.









No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI