EYI NI BI KOMISANA OLOPAA IPINLE OGUN, ALUKORO E SE GBA AWOODU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 21, 2018

EYI NI BI KOMISANA OLOPAA IPINLE OGUN, ALUKORO E SE GBA AWOODU

Yinni-yinni k'ẹni o se min in, lo n mu kori ya, won yi loro to lo nibamu pelu bi ajo eleto aabo agbaye kan, iyen Africa Security Watch se fun komisana olopaa ipinle Ogun, Ahmed Iliyasu ati alukoro e, Abimbola Oyeyemi ni awoodu gege bi awon to n sise eeto aabo daadaa lorileede Naijiria.


Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ni won fun lawoodu irawo oni goolu, iyen Golden Star Award gege bi ẹni to mo bi a ti n ṣawari awọn odaran, towo sí n tẹ wọn ni gbogbo Afrika.

Bẹẹ ni alukoro olopaa, Oyeyemi ni ti e gba awoodu gege bi alukoro olopaa to dara ju lorileede Naijiria.

Yato si awọn mejeeji yi, alaga ẹgbẹ to n gbenuso fawon araalu lodo olopaa, iyen Police Community Relations Committee (PCRC), Alaaji Ibrahim Olaniyan naa gba awoodu gege bi ajo to n seranlowo ju fawon olopaa.

AWIKONKO gbo pe nibi ipago ti ajo Africa Security Watch se, eyi to je eleekeedogun iru é, to waye ni ile itura Labranda Koral Beach niluu  Banjul lorileede Gambia eto  naa ti waye.

PÍN-IN KÁÀKIRI