Lati tan imole sí isakoso osibitu awọn aloukoni tiluu Ado-Ekiti, iyen Ekiti State University Teaching Hospital (EKSUTH), Gomina ipinle naa, Dokita Kayode Fayemi ti gbe igbimo eleni-mejo kan dide lati tan imole sí bí isakoso osibitu naa se lo sí laarin odun 2013 sí asiko yi.
Ninu atejade ti agbenuso fún Gomina Fayemi, Ogbeni Olayinka Oyebode fi sita láì pe yi, eyi ti eda é tẹ AWIKONKO lowo se so, o ni won fe e mo awon adojuko to n koju osibitu naa, ati bi won se n na awọn owo to n wole fún wọn láti ọdún 2013 sí asiko yi.
Awon igbimo naa ni: Ọjọgbọn (Arabinrin) Ebun Adejuyigbe, alaga; Ọjọgbọn Deji Agboola; Ọjọgbọn Simi Odeyinka; Ọjọgbọn Ayo Omotoso; Dokita Walter Yemi Olatunde; Ogbeni Ayoola Owolabi; Ẹnjinia Tunde Alabi ati Ogbeni J.A Obaparusi toun je akowe igbimo naa.
Lara awon nnkan ta a gbo pe igbimo naa yóò topinpin ni;
(i) Bi won se n sakoso to loorin ni osibitu naa nipa ojuse igbimo isakoso (Governoring Board), oludari agba fún ètò ìlera (Chief Medical Director) atawon agbaagba to di ipo mu, iyen principal Officers.
(ii) Bi won se n sakoso owo nina, to fi mo owo tijoba n fún wọn, ati owo ti won n pa lapo ara wọn bọ ya o ba ilana mu.
(iii) Bi won se n pin owo s'awọn ibi to ye, paapaa awon special grants ati eyawo ti won fún wọn fawon iṣẹ akanse, ati lati mo ipele ti iru iṣẹ bẹẹ dé dúró, ati bi won se ku oju oṣuwọn to.
(iv) Ona ti won n gba ati awọn agbekalẹ won lati ríi pé àwọn osise atawon akekoo n se ojuse won lai tapa si ofin agbekale osibitu naa.
AWIKONKO gbo pe ọsẹ merin pere láwọn igbimo naa yóò lo lati fi se awon iwadii.