AWIKONKO: Nje a le mo yin?
HAMITTON: Oruko mi ni Kunle Hamilton, emi ni Aare soosi El-Shaddai Ville
lagbaye, emi naa tun ni alakoso soosi Praise Ville, abe soosi Ijo Mimo ti
Kristi lati Orun Wa, iyen Celestial Church of Christ ni mejeeji wa.
AWIKONKO: E je ka mo die nipa yin
HAMITTON: Wel, opo nnkan lo wa nipa mi, sugbon mi o ni fe e so o
tan, maa kan fun un yin ni ifaara nipa mi. Mo lo sileewe alakobere ati girama,
bakan naa ni mo tun lo sileewe fasiti nibi ti mo ti ko eko nipa Philosophy ati
eto ikansira-eni, iyen Mass Communication, eyi ti mo se fi gba oye ojogbon tii
se PhD. Iyawo kan ni mo fe. Eyi to po ju ninu igbesi aye mi, ise akoroyin ni mo
fi se. Mo ti lo ogbon odun o le die gege bi akoroyin. Ileese iwe iroyin
Vanguard ni mo ti bere ise akoroyin mi, ti mo si pari e sileese iwe iroyin
ThisDay gege bi Olootu. Mo maa n ko awon nnkan to n sele lawujo, eyi gan an lo
so mi di olokiki nidi ise naa. Ko tii ju odun mejila lo ti mo fise naa sile
patapata.
AWIKONKO: Ki lo fa a ti e fi kowe fise oniroyin sile?
HAMITTON: En, mo le so pe igba to ba n ye ni laa n kuro lori itage,
idi ni yii ti mo fi fise naa sile. Mo ti kopa ribiribi nidi ise yi, mo si ti
ilana temi funra mo si ro pe gege nnkan to ye ki eni to ba ni iberu Olorun se
ni yii, ati pe ko dara ki eni ti a gba si ise tun maa se ise min in mo ise ti a
gba a fun un. Ko dara ki Mo ro pe ko bojumu. Ise iranse mi tun jinle sii nigba
ti mo kowe fise sile lodun mejila seyin, ati pe nitori pe mo fe e koju mo ise
iranse ti a fi ran mi lati orun wa, mo ni lati tete fise akoroyin sile.
AWIKONKO: Se ka so pe Olorun lo pe yin, abi eyin lo wun lati
sise f’Olorun?
HAMITTON: E seun, Mo ti gbiyanju lati mo iyato laarin eni to ni ipe
Olorun ati eni to ni agbara lati da soosi sile. Eeyan le ni ipe Olorun, ko ma
ni agbara lati bere ise iranse. Eeyan si le ma ni ipe Olorun, ko si ni agbara
lati bere ise iranse. Eeyan si le ni ipe ko je lesekese ko lo maa bere ise
iranse. Ni ti temi, mejeeji ni mo ni. Ipe ti mo ni bere latigba ti won ti bi
mi. Mo ranti gege bi nnkan ti Mama mi so fun mi pe asiko tawon ro pe awon ti
dawo omo bibi duro lawon loyun mi. kii se pe won dee de loyun mi, Ojise Olorun
kan lo n waasu aarokutu kaakiri adugbo ti Mama mi n gbe, iyen ni Oke-Ado niluu
Ibadan. Ojise Olorun naa to je Obinrin lo duro lenu ona ile Mama mi to si bere
sii so pe Arabinrin kan wa ninu ile yi, eni naa ro pe oun ti jawe ninu omo
bibi, sugbon Olorun fe e ran iranse e kan lati ara Obinrin naa, nigba ti Olorun
maa jeri ara re, mama mi ti won ro pe awon ti dawo omo bibi duro sakiyesi pe
awon ti loyun.
Ki n ma paro fun un yin, fun bii odun mokanlelogun leyin ti won
bi mi, mi o ro pe Mama mi ri ipa wi pe awon bi iranse Olorun to tun je Wolii
lara mi. Inu soosi aguda, iyen Methodist ni won bi mi si, ibe naa ni mo dagba
si, sugbon ebun Olorun ti Wolii ko farahan ninu aye mi, afigba ti mo darapo mo
soosi alaso funfun, iyen Celestial Church of Christ lodun 1985. Nigba to si
farahan ninu aye mi, lesekese ni Olorun ti bere sii lo mi fun ise e, ko da a,
to de bii wi pe gbogbo odun ti mo fi padanu lai sise Olorun yi ni Olorun funra
e da pada fun mi, tawon eeyan si ro pe mo ti bere tipe.
Ko pe ti mo fi di adari ninu soosi Sele, ti mo fi di Wolii, mo
si le so fun un yin pe lati ojo akoko ti mo ti wonu soosi Sele, ni ohun ti jade
wa pe ise iranse mi ninu aye yi, adari ni mo maa se, ati pe Olorun fe e lo mi
ninu soosi naa ni. Ipe ti Olorun pe mi je ipe asotele, sugbon ebun ti Olorun
fun mi je Oluso-Aguntan. Oluso-Aguntan yi je gege bii Pasito, emi o si fe e se
Pasito, bee ni mi o fe e se Oluso-Aguntan. Mi o nife sii pe ka sese maa woju
awon eeyan ka to o jeun, ka maa duro de owo osu ka to o le ra nnkan to ba wun
wa, tabi lati toju awon ebi mi. fun idi eyi, mo ni lati wonu aawe ati adura lo,
mo si ba Olorun soro, bee ni mo tun jeje. Mo gbadura kikan-kikan s’Olorun, o si
gbo adura mi nigba naa debi pe emi ni mo akekoo to peregede julo ninu eko nipa
Philosophy ni fasiti ipinle eko, iyen UNILAG. Mi o fe e duro lori eko yi nikan,
nitori naa, mo tun ronu nnkan min in ti mo le se, lo je ki n loo kekoo nipa ise
oniroyin ati ikansira-eni, ti a mo si Mass Comm.
Nigba ti mo si de inu egbe akoroyin, lesekese ni mo di gbajumo,
ati pe ni kete ti ileese Vanguard ti mo ba sise nigba naa fun mi ni aaye ninu
iwe iroyin won lawon eeyan n pe mi lotun ati losi, tawon eeyan si mo mi.
Mo le so fun un yin pe bi e ba gbadura s’Olorun Oba, O n gbo,
Olorun gbo adura mi, o si fun mi loruko meji, O fun mi ni El-Shaddai Ville ati
Praise Ville. Mi o mo itumo El-Shaddai Ville, sugbon mo nnkan ti Praise Ville
tunmo si, idi ni yii ti mo fi gbe eka kan kale ti mo pe ni Praise Ville. E je
ki n jewo fun yin pe, bo se n ku die ki n pe ogota odun laye, soosi Sele ko mu
nnkan ti won je lokunkundun.
Awon nnkan ti ko dara lawon eeyan n ka ju eyi to dara nipa won
lo, kii se pe ko si nnkan ti ko dara nipa awon soosi to ku tabi awon elesin to
ku, sugbon awa ko bikita fun ti wa. Mo je okan lara awon ti ko fe ki won maa ri
nnkan idoti mo, mi o si feran nnkan to le ba mi loruko je, idi ni yii ti mo fi
sa kuro ninu soosi sele leemeta otooto. Eemeta otooto ti mo fi sa kuro yi ni
Olorun fi ran awon Wolii ti ko ti e mo mi ri rara si mi lati so fun mi pe mo ni
lati pada sibi ti mo ti sa kuro, wi pe ibe ni ibi ti Olorun ran mi si lati jise
fun un.
Awon eeyan le so orisirisi ona ti won gba wonu soosi Sele,
elomin in le so pe won bi oun sinu e ni, elomin in le so pe aisan tabi isoro
kan lo gbe oun debe ti won fi juwe Sele fun un, toun si ri igbala, sugbon temi
ko ri bee rara, mi o ni isoro to n le mi kaakiri. O ku ose kan ki n lo fun
agunbaniro ni mo darapo mo won. Mo fe e fi da a yin loju pe bi kii ba a se ipe
El-Shaddai Ville to je eka ipe ti Olorun fi ran mi ni, mi o ni nnkan ti mo n wa
ninu soosi Sele nitori pe mo ni opolopo nnkan ti mo fe e se, eyi ti ilana Sele
ko gba laaye ninu agbekale won. Mo gbiyanju lati gbe idanilekoo nipa adari,
iyen Leadership Training kale, nigba yen, ko tii seni to n se iru nnkan bee,
eyi to fe e fara pe e ni soosi kan ti won pe ni DayStar, sugbon ko jo ara won
rara.
Kii se pe bo ya mo n wo awokose, idi ni yii ti awon agbaagba
Sele ko fi gba a wole, mi o si setan lati da wahala sile nibe, idi ni yii ti mo
fi gbe e segbe kan. Bi mo se n baa yin soro yi, ise iranse El-Shaddai Ville mi
ti pe odun metadinlogun (17years), nigba ti asiko si to, Olorun ran mi leti eje
ti mo je, odun meji seyin ni mo da soosi akoko mi sile niluu Berlin lorileede
Germany, Olorun si san gbogbo owo to ye ki n san lati fi da a sile lai na owo
kankan, ti mi o si tun kuro niluu Eko. O ti n lo si ipari odun to koja nigba ti
Olorun so pe asiko ti to lati da Praise Ville sile ni Naijiria, a si bere pelu
isin ta a pe ni Celestial Showers losu kinni in odun yi. Osu
kejila to m bo yi lo maa pe osu mejila ta a da a sile, Olorun si so fun mi pe
losu kinnin in odun 2019, ka gbe e s’agbaye, idi ni yii ta a fi gbe eto kan
kale, eyi ta a pe ni Celestial
Showers Convention, to maa waye ni papa isere apapo, iyen National Stadium niluu Eko.
AWIKONKO: Bawo ni igbesi aye yin leyin te e fi ise iroyin sile?
HAMITTON: Wel, mo nife sii lati ba a ileese sise, idi ni yii temi
naa fi da ileese temi sile, nibi ti mo ti n gbenuso fawon ileese lorisirisi, mo
si ni oga to po. Mi o mo idi ti opo awon Pasito fi n sise iranse won lona ti
won n gbe e gba lorileede yi, ati pe a ko le fe iru e lawon orileede tie se po
ju si. Ise iranse je nnkan teeyan gbodo fara jin fun, ki Pasito to o le ronu
ohunkohun, o gbodo koko ronu awon opo atawon alaini to wa ninu soosi e, ko too
sese ronu nipa ara e. Ni temi, idi ni yii ti mo fi da ileese mi sile, ki n le
ni aaye fun ara mi daadaa. Mo ni oga to po, awon ti mo n ba sise lawon oga ti
mo ni, mo si tun ni aaye daadaa funra mi.
AWIKONKO: ki lawon ipenija gege bi akoroyin?
HAMITTON: Ise akoroyin gege bi mo se rii je ise to ni ayo ninu. Mo ti je
eni to n ko iroyin nipa awon nnkan to n sele lagbegbe, iyen Society writer. Mo ti ko orisirisi nipa awon araalu, awon oloselu, awon
eeyan ati bee bee lo, mi o si figba kan ri kabamo nipa awon nnkan ti mo n ko
jade fawon eeyan lati ka. Mo gbiyanju lati rii pe mi o se ojuusaaju ninu awon
nnkan ti mo n ko, ko si seni to fesun kan mi ri. Sugbon eyi to je gege bi
ipenija fun mi ni pe, gege bi Olootu, mo ni lati bawon eeyan sise, mo lawon
akoroyin to n ba mi sise, mo si gbodo fokan tan won. Okan lara awon akoroyin yi
lo wa a ko iroyin kan to kun fun iro, to si je pe eni to ko o nitori e dunkoko
lati gbe ileese ti mo n ba sise nigba naa lo sile ejo. Aare egbe PMAN leni naa,
mi o ni daruko e fun yin. Mo ni lati gba nnkan ti akoroyin mi yi ko ranse si mi
gbo. Nigba ti wahala naa de, mo ni lati se iwadii mi, leyin o reyin lo sese wa
a jewo fun mi pe iro ponbele loun ko jade. Won ni lati da mi duro fungba die,
ti mo si gba pe emi ni mo jebi, nitori pe emi ni mo gba keeyan gbe ayederu
iroyin koja lara mi. O dun mi gan nitori pe mi o feran ki n maa lo dobale bebe,
awon nnkan temi gan an ko funra mi, mi o bebe ri, eni to ba fe e dunkoko, maa
so fun un pe ko je ka pade ni kootu. Ipenija nla ti mo ba pade re e. Nnkan to
tun je ko je ipenija nla fun mi ni pe ileese ti mo n sise fun ko daabo bo mi,
nitori pe emi ni mo jebi, ko ye ki n gba iru nnkan be laaye, mo ni lati gba pe
ki won dami duro fungba die. Nnkan to si ye kawon ojogbon maa se gan an niyen.
Leyin ose meji, ti won da mi duro ni won pe mi pada, won si da akoroyin naa duro.
Mo si pada sori ese mi. leyin odun die ti mo pada senu ise ni mo kowe fise
sile. Lai je eyi, mo gbadun ise naa gidigidi. Ati pe ise yi lo mu rin irin ajo
kaakiri ile Afrika, o si tun fun mi lanfaani, paapaa awon nnkan ti mo nilo lati
da ileese mi sile.
AWIKONKO: Amonran yin fawon akoroyin to n bo lona?
HAMITTON: Ise akoroyin je ise to dara gan an, to si se e gberaga.
Amonran mi ni pe eni to ba fe e sise akoroyin gbodo je eni to gba eko daadaa.
Kii se dandan keeyan niwe eri ko too le sise akoroyin, sugbon eni naa gbodo gba
eko gidigidi. Awon ilana atawon agbekale ise yi koja keeyan niwe eri tabi
keeyan ma ni. Beeyan ko ba gba eko lori ilana ati agbekale ise yi, afaimo keni
naa ba ara e lewon tabi ko san faini ti agbara re ko nii gbe. O je iso ta a fi
n so awon araalu, iyen watchdog. Awon
oniroyin gbodo maa ran orileede won lowo, won gbodo maa ran awon olopaa lowo
lati sise won, won gbodo ran awon oloselu lowo lati sise won, bee ni awon si
gbodo maa ran awon agbejoro lowo ki ise won le rorun lati se.
Maa gbawon lamonran pe ki won ma se lowo ninu iwa ibaje, ko seni
to le fesun kan mi pe mo gba owo riba lowo oun ri, mi o si ro pe mo nilo awoodu
fun un. Mo ni owo osu ti mo n gba. Ti m ba sise leyin ise akoroyin, teni naa si
wo o pe, o ye koun gboriyin fun mi, mo ro pe iyen dara, sugbon wi pe ki n beere
lowo e, ki n si dawo iroyin ti mo fe e ko duro, tabi ki n paaro akole mi, nnkan
idojuti niyen, kii se fun akoroyin nikan, bi ko se fawon ise min in.