Ojo Tosde ana ni ajo INEC nipinle Ogun pa ariwo yi sita fawon araalu pe kaadi idibo alalope ti ko din ni egberun marun aabo )567,637) lo wa nile kaakiri woodu to wa láwọn ijoba ibile nipinle Ogun tawon eeyan ko tíì gba.
Ogbeni James Popoola to je akowe ajo naa lo kede sita niluu Abeokuta nibi ìpàdé awọn otokuulu ti won se ninu gbongan sinima ti June 12, Kuto lati fi to awon èèyàn leti nipa imurasile Ajo naa fún ti idibo to n bọ.
O wa je kó di mimo pe gbigba kaadi naa yóò bèrè pada laarin ojo kefa sí ojo kejila osu yi.
No comments:
Post a Comment