Béèyàn bá jẹ furọ adiẹ, ko da a, ko le ka to bi Fatima Suleiman ati Salaudeen Ibrahim se n ka ni olú ileese olopaa ipinle Kwara to wa niluu Ilorin lojo Tosde to koja yi.
Kò sí nnkan meji to kawon mejeeji yi máa kà bi ajé to je eewọ bi ko se basiri won se tu s'awọn olopaa lowo pe won sóowò tita ati rírà ibi omo, ti won sì fi n soogun owo fawon eeyan to ba nilo.
Opo awon ero to wa nibi ti Komisana olopaa ipinle naa, Bolaji Fafowora ti foju awọn odaran yi hàn fawon oniroyin ni won lanu sile, ti won ko si le tete pa a se nígbà tawon mejeeji n ka pe looto láwọn fe e fi ibi omo soogun owo.
Gege bi iroyin to te AWÍKONKO lowo se so, lojo kokanlelogbon osu to koja ni won sáré gbe ìyáálé ilé kan, Bashirat Jimoh ti won lo n robi omo tuntun lo sí osibitu ti Fatima ti n sise ni nnkan bi aago meji osan.
Oko Bashirat, Abdulfatai Jimoh lo gbe iyawo é lo sí osibitu naa ti won pe ni Capstone to wa lagbegbe Taiwo niluu Ilorin lati sise abe fún nitori ti won ni ko le da omo naa bi.
Bi won se sise abe naa tan ni dokita to sise abe naa, Jamiu Mohammed gbe ibi-omo fún Fatima pe ko gbe é fún baba omo tuntun naa, iyen Abdulfatai, sugbon kaka ko gbe e fún ùn, ile Ibrahim to n gbe lagbegbe Ajaka lo gbe é lo.
Nigba ti baba omo mo ri ibi omo e gba, lo ba lòó f'oro naa to awon olopaa leti, tawon yeni sì bẹrẹ iṣẹ iwadii, ko to di pe asiri Fatima tu, toun naa sí jewo pe Ibrahim loun ta a fún, ati pe ko tii foun lowo titi dasiko t'asiri tu.
Egberun lona ogun (20,000) naira loun ati Aafa naa jo sadehun sugbon ko tii foun lowo, o lòó ti pe ti Ibrahim ti ran oun nise naa, to sì jẹ pé ọsẹ meji seyin loun ṣẹṣẹ rí iṣẹ naa je fún ùn.
Ibrahim ninu oro ti é naa so pe looto loun ran Fatima nise, ati pe oògùn owo loun fe e fi se. Bẹẹ lọ so pe enikan loun jo'gun iṣẹ náà lowo e.
Oga olopaa naa, Fafowora ti wa a ṣèlérí pé láì pe láwọn yóò foju awọn odaran meji naa balẹ ejo.