Bo
tile je pe ayeye idalola ti won fi yan Alagba a Samuel Oladele Awolude
gege bi Alagba ati Eni-Owo Ọlọlajulọ fun soosi, The Blessed New
Jerusalem Church of Christ sí n lo lowo lonii ojo kewaa osu kọkànlá ninu
soosi naa to wa ni Kuto niluu Abeokuta.
Bẹẹ,
ẹsẹ ko gbero ninu soosi naa bi a ti n ko iroyin yi nitori pe kaakiri
agbaye láwọn èèyàn ti wa a yẹ Baba Samuel Oladele Awolude ṣii lati fi bù
ọlá fún ùn.
Opo awon eeyan ni won sì n ki baba naa fún ti ayeye idalola naa, eyi ti won fi ìsìn onígbàgbọ bere é.
Nigba
to n wàásù, Bisoobu Tunde Akin-Akinsanya to je alaga ẹgbẹ onigbagbọ,
iyen Christian Association of Nigeria, CAN so pe kii se pe won dee de
yan Alagba Awolude sí ipò náà, bi ko se pe nnkan ti Olorun ti ko ni.
Bisoobu
Akin-Akinsanya gba Alagba Awolude lamonran pe ko je Eni-Owo Ọlọlajulọ
(Primate) to n tan imole, ko sí lo ipò náà láti fi tan imole sí gbogbo
ayé nitori ipo naa kii se ipo kekere láwùjọ ìgbàgbọ.
Ninu
ese bibeli to fi wàásù, Iwe Matiu ori karun, ẹsẹ kerindinlogun (Matthew
5:16) lo ni gege bi Bibeli se fìdí è mule pe omo imole láwọn je, awọn
onigbagbo gbọdọ máa fi àpẹẹrẹ imole Olorun hàn fawon eeyan, paapaa ijo
Olorun.
"Ojúṣe
fún ìjọ ati ojuse sí ebi yin láwọn ojúṣe meji ti é ni, é kò sì gbọdọ
gba nnkan ti yóò dá emi yin legbodo. É ṣe iwọn ti é le ṣe, ki é sí fi
eyi to ku sile.
"1Peter
2:9, É kò gbọdọ jẹ kí okunkun fara hàn lara yin, nitori ipo ti a gbe
yin si lónìí, ipo to gbọdọ tan imole ni. Ọlọrun fẹ ká tan imole sí
jeneration yin, é tí yato sawon iransẹ Olorun to ku, nitori a ti gbe e
yin soke ju awọn iransẹ Olorun to ku lo.
"Kii
se nipa iriri yin tabi eko tabi owo ti é ni lo je ki won Yan yi, bi ko
se pe Olorun ti ko latibere pẹpẹ pe é máa di Olùṣọ àgùntàn to dára láti
darí àwọn èèyàn rẹ sọdọ é.
"É
kò gbọdọ já Ọlọrun kule, imole yin si gbodo tan kaakiri agbegbe yin,
kawon eeyan sì lè máa topase yín wá sọdọ Ọlọrun. É gbodo da yato ninu
idari ati isakoso yin. E gbiyanju lati gbe ohun tuntun wọnú ijo yi.
"Mo
ro eyi eeyan láti fowosowopo pelu Primate tuntun yi ko le muu yin lo
sile tuntun, nitori pe láì sí ifowosowopo pelu é, ko le ṣí ilosiwaju."
Bakan
naa lo tun ao pe "Oju kokoro lo pa Balaamu, nitori naa, é gbodo sa fún
ojú kòkòrò ko ma baa re yin lulè lọnà olugbagbọ yi."