AWOTELE LAWON OMO YAHOO TUN N JI KA BAYI O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 12, 2018

AWOTELE LAWON OMO YAHOO TUN N JI KA BAYI O

Beeyan ba wa nibi tawon toogi ti n lu odomokunrin kan tojo ori e ko tii ju odun marundinlogbon lo, eni ti won fesun kan o ka pata, iyen awotele awon obinrin losan gangan, yoo ba a kaanu lori bi won se lu aye e baje.

 
Odomokunrin naa ta a ko tii moruko e dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan la gbo pe o fi ilu e, iyen Obowo nipinle Imo sile, o si gba agbegbe Umuokoro lo lati loo ji awon pata naa ka lori waya ti sa a sii.

Ohun tawon to gbe iroyin naa si AWIKONKO leti n so ni pe awon omo Yahoo ni won ran an nise buruku naa, ati pe oogun owo ni won fe e fi se.

 
Awon eleyinju aanu kan la gbo pe won gba a sile nigba to ku die ki won dana sun un, ti won si loo fa a le awon olopaa lowo.

Gbogbo akitiyan lati ba agbenuso olopaa nipinle Imo soro lo ja si pabo titi dasiko ta a sakojoo iroyin yi tan.

PÍN-IN KÁÀKIRI