Ipakupa láwọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti iileeko gbogbonise ti Rufus Giwa to wa niluu Ọwọ nipinle Ondo n pa ara won danu lasiko yii, lati ọsẹ to koja ni wahala náà sì ti bere laarin won.
Iroyin to te AWÍKONKO lowo láì pe yi fìdí è mule pe awon egbe okunkun Ẹiyẹ ati Aiye ni won n kọjú ìjà sira won, ti won sì n fowo agbara hàn ara wọn.
Ohun tá a gbo ni pe bo tile je pe ko tii seni to le so pato ohun to fa ìjà won, sugbon lara awon iroyin to te wa lowo so pe nitori obinrin ni won se n f'iku wa ara won kaakiri, ti won sì ni agbára ileese olopaa ipinle naa ko tíì ka won.
Àdúgbo kan ti won pe ni Right Link Villa lagbegbe Okanlawon láwọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti pade ara won lai pe yi, tó sì kó ibẹrubojo bawon araalu, to di pe onikaluku bere síi sa asala fún èmí ara é.
Ọkan lara awọn omo ẹgbẹ okunkun ti Aiye tá a ko tíì moruko é dasiko tá a sakojopo iroyin yi tan ni won mu balẹ lasiko ikọlu naa.
Fún bíi wakati meji aabo la gbo pe gbogbo adugbo naa fi pa lolo, tí eṣinṣin ko fo rara débi pé èèyàn yóò rìn.
Bẹẹ la gbo pe lose to koja, lagbegbe Ijapo niluu Akure ni won ti koko da wahala nla sile, ti won pa ẹnikan naa sibe.
Awon olopaa la gbo pe won pada wa a gbe oku naa lo sí mosuari.
No comments:
Post a Comment