Gege ba a se gbo, lati ipinle Oyo la gbo pe awon agunbaniro marun naa ti won pe oruko won ni; Abiola Temitope, Olubisi Adekanmi, Jose Temitayo, Folarin Opeyemi ati Shonibare Ademola ti kuro, ti won si n lo sipinle Rivers ati Akwa-Ibom.
Opopona Oweri si Port-Harcourt, iyen lagbegbe ijoba ibile Ohaji/Egbema nipinle Imo la gbo pe awon agbenipa yi da moto won duro, bi won si se ri aso agunbaniro lara won ni won ti pe won bole, ti won si fe e gbe won wonu igbo lo, lati loo pa won soogun owo.
Opelope awon olopaa ta a gbo pe asiko ti won n ko won lo sibi ti won ti fe e pa won lasiri won tu, ti won si ri awon agunbaniro maraarun yi gba pada.