Gege
ba a se gbo, ko tii ju ose meta ti won gba Daniel si soobu naa to wa
ladugbo Asero niluu Abeokuta pe ko maa bawon bojuto soobu naa, to fi
pawopo pelu awon adigunjale lati wa a ja soobu naa, ti won si ko ero
amohunmaworan ti won n lo pe komputa, iyen monitor nibe salo.
Ogbon
ojo osu kesan an to koja yi ni oga to gba Daniel si soobu, Arabinrin
Titilayo Ero gba tesan olopaa lo lati loo foro naa to won leti, idi ni
yii tawon olopaa fi ranse pe Daniel pe ko wa a so nnkan to mo nipa e.
AWIKONKO gbo pe se ni Daniel n koko paro fun won, sugbon ninu oro to tun n
so lo je ki won fura sii pe o see se ko mo nipa e, idi ni yii ta a gbo
pe won fi dana iya fun, to si jewo pe oun loun ran awon adigunjale naa
lati wa a fo soobu naa.
Daniel
so pe monito mejilelaadota (52) lawon ji ko, ati pe ore e oun kan to n
je Smith Ajao lo sagbateru bi won se ta awon ero naa danu. Daniel lo
lewaju awon olopaa lo sile Smith to wa ni Sango Ota, touj naa si jewo pe
looto ni, ati pe awon ti ta a danu si Ikeja nibi ti won ti n ta
orisirisi eto igbalode to fi mo komputa.
Nigba
ti won de Ikeja, mejidinlaadota ni won ri gba pada ninu awon eru naa,
ta a si gbo pe Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti pase pe ki won tete loo
foju awon odaran naa bale ejo.