Minisita foro eto eko lorileede yi, Malam
Adamu Adamu ti so pe ajo to n sagbateru eto eko lorileede yi, Universal Basic
Education Commission (UBEC) ti setan lati gbe bilionu 142.58 naira sile fun
idagbasoke eto eko orileede yi.
Adamu lo
fidi oro yi mule niluu Kaduna lai pe yi nibi ipade ti won se peluu awon Oba
alaye, agbaagba ati oloye ile Ahusa fun ti awon akekoo ti won ko ri ileewe lo,
eyi ti won pe ni Out-of-School.
Ipade olojo
meji naa la gbo pe ileese to n ri soro eto eko lorileede yi, Federal Ministry
of Education, Universal Basic Education Commission, National Commission for
Mass Education and Sultan Foundation for Peace and Development, in collaboration
with United Nations Children’s Fund (UNICEF) sagbateru e.
Adamu ni
laarin odun 2016 si asiko yi ni banki agbaye ti gbe milionu $611 sile lati fi
ran awon omo ti ko lo sileewe lowo, lati le je kawon naa kopa ninu eto eko
orileede yi.