...Awa la n ran Ijoba lowo – Dokita Giwa
Egbe alajumose oluranlowo ti agbegbe Gbagada
nni, Rotary Club of Gbagada gbe eto
iranlowo olojo meta kale fawon to ni ailera kan tabi omin in lago ara won,
paapaa awon to ni ipenija ara lojo Tosde, ojo kejidinlogun si oni ojo Abameta
Satide tii se onii, ogunjo osu kewaa. Eto iranlowo naa lo nii se lati sayewo
ailera to n ba awon araalu ja, ti won si tun n fun won lanfaani lati loo gba
itoju to pe ye lawon ileewosan aladani ti won n ba dowopo kaakiri orileede yi.
Gege bi AWIKONKO se gbo, eto naa la ayewo
ilera ofe fawon molebi, eyi ti won pe ni Family
Health Care la gbo pe odoodun ni won n se e, ati pe odun kefa re e, ti
won ti yan ile iwosan ijoba ti Gbagada niluu Eko, iyen Gbagada General Hospital laayo fun lilo lati maa
fi seranlowo ayewo ofe fawon ara Gbagada ati agbegbe e, to fi mo awon to wa
lona jinjin rere.
Opo awon ara agbegbe Gbagada to je anfaani
eto naa, ti won b’AWIKONKO soro lojo Friade ana ni Osibitu Jenera ni won je ko
di mi mo pe iru e ko tii sele ri, ati pe iranlowo ti egbe naa n se fawon araalu
lodoodun, ko ni asaaju nitori pe pupo lawon to ti gbadun pelu ayewo ofe ati
itoju ofe ti egbe naa se fun won.
Ninu oro Ogbeni Bashiru Pedro to ni ipenija
oju, eni to ni oun kii ri eeyan daadaa, yala eni naa sunmo on oun ni tabi pe
eni naa wa loni jinjin, o ni oun ko koko gbagbo nigba toun gbo nipa eto naa,
sugbon nigba toun ba Aare egbe naa, Dokita Giwa pada ni nnkan bi ojo marun
seyin, lo fokan oun bale pe koun wa, nitori pe gbogbo isoro toun ni ni yoo
dopin.
Ogbeni Pedro so pe egberun lona egberun owo
naira loun tin a si oju oun, sugbon to je pe pabo lo n ja si. O nigba kan wa
toun tun loo gba abere leemeta otooto gege bi won se salaye foun, o ni sibe,
oju oun ko yi pada kuro nib o se wa.
O tun fi kun oro e pe, egberun meji aabo
(2,500) naira pere ni egbe Rotary Club of
Gbagada ni koun mu dani lati loo fi gba itoju si oju naa nileewosan kan ti
ko daruko fun wa, to si ni boun ba fe e lo gba iotju naa, o kere ju, oun gbodo
ni egberun lona igba (200,000) naira.
Arabinrin lawal Adedoyin toun naa tun je okan
lara awon to je anfaani yi, eni to so pe aisan to n ba oun ja lago ara ti se
die, toun si tin a opolopo owo sii, sugbon to n je pe bakan naa ni, o ni owo ti
won ni koun mu dani lo si osibitu toun yoo ti lo gba itoju ko to nnkan rara, ko
da a, ko too se obe sinu ikoko.
Obinrin kan toun naa tun soro so pe bo tile
je pe kii se oun ni nnkan n se, bi ko se omo oun, o ni looto ko fi bee si owo
lowo oun lati toju omo naa, sugbon iranlowo ti egbe naa se foun koja afenuso,
to si je pe won foun lawon nnkan ti yoo je ki omo naa gbadun leyin ti won
sayewo fun un tan.
Lati fi onte lu ise akanse ti egbe naa n
se, Ogbeni Akinwale Ojutola to je eni ti
ipo Aare naa kan lodun to n bo je ko di mi mo pe iranlowo ti egbe naa n se
fawon araalu ko kere, to si je pe awon sese bere ni, nitori pe ko tii ju odun
mefa lo tawon mu Osibitu Jenera ti Gbagada ni okunkundun.
Ninu iforowero pelu Aare egbe naa, Dokita (Arabinrin)
Basirat Giwa lo ti je ko di mi mo pe egbe awon n se iranlowo fun ijoba ipinle,
paapaa ijoba orileede yi ni, nipa sise awon ojuse to ye ki ijoba se, bo tile je
pe ijoba ko le se gbogbo e tan fawon araalu, tawon si ni lati dide lati
AWIKONKO: E JE KA MO YIN LEKUNRERE?
GIWA: Oruko mi ni
Dokita Basirat Giwa, emi ni Aare egbe alajumose tiluu Gbagada (Rotary Club of
Gbagada) nipinle Eko. Inu osu keje odun yi ni mo di Aare egbe yi. Dokita to n
sayewo ati itoju oju oju ni mi. gbogbo nnkan to ba nii se pelu oju ni mo n se e pelu iranlowo Olorun.
AWIKONKO: KII
SE AKOKO RE E, KI LO BI ETO YI GAN AN?
GIWA: E seun, se
e ri eto yi, odoodun la maa n se e, a si pe e ni Rotary Family Health Day. A ti
muu gege bi ojuse wa pe fun ojo meta leekan lodun, a maa gbe eto ilera ofe kale
fawon eeyan kaakiri orileede yi, paapaa julo bi a tun ti ta gbongbo de koja
orileede yi, gbogbo awon eka egbe yi ni won maa mu adugbo kan ni agbegbe won
lati gbe iru eto bayii kale, ti won si fawon eeyan ni ayewo ilera ofe lai gba
owo lowo enikeni. Awa ni ti wa, Rotary Club of Gbagada, ati mu Osibitu Jenera
ti Gbagada nipinle Eko gege bi ojuse wa, paapaa pe ka maa lo o lati fi dawon
eeyan lohun lati nnkan bi odun mefa seyin. Sugbon nitori pe emi ti mo je
onisegun nipa oju, mo yan ojo kan ninu ojo meta soto lati fi se ayewo oju fawon
eeyan to ba wa. A si ti se orisirisi ipolongo fawon eeyan kaakiri lati wa a je
anfaani yi.
AWIKONKO: BAWO
LE SE N POLONGO FAWON EEYAN LATI LO MAA SAYEWO ILERA WON L’OSIBITU, ATI PE IPA
WO NI EGBE YIN N KO LATI DENA AARUN TABI IKU OJIJI?
GIWA: Gbogbo eka
to nii se pelu igbesi aye eeyan ni egbe wa n da si, ti a si n dide iranwo fawon
eeyan ti a ba rii pe won nilo iranlowo. A tun n gbogunti ise ati osi laarin ilu,
paapaa awon nnkan to le mu alaafia ati atunto de ba ilu (Peace and Conflict
Resolution). Okan lara awon nnkan ti a se ninu egbe wa kaakiri ni eyi ti e ri
ta a n se yii. Kii se pe ka kan maa ye won wo lasan ni, bi ko se lati tun ran
won lowo nipa bi won yoo se gba itoju, a tun n ba won soro lori bi won yoo se
maa toju ara won, paapaa nipa bi eto ilera se se koko ati pataki. Lati bi odun
metalelogbon seyin bayii ni egbe wa ti wa lara awon egbe to mu gbigbogun ti aarun
ti a n pe ni Polio, eyi to maa n se awon omode. Ni odun die si asiko yi,
Naijiria maa kuro laarin awon orileede to ni aarun yi. A si tun n rii pe awon
eka min in naa to nii se pelu eto ilera la n baa won eeyan soro lori bi won se
le dekun e.
AWIKONKO: BAWO
LAWON EEYAN SE MU ETO YI LOKUNKUNDUN TO?
GIWA: Ko da a, o
koja afenuso, awon eeyan dide lati wa, ti a si rii pe won n fe ki opin de ba
orisirisi aisan ati aarun layika won. Asiko ti a wa yi ti lujara won (ICT),
kaakiri agbaye ni won ti n fi awon nnkan ti a se ranse sori ayelujara. Awon eeyan
si n dide wa. O ti n lo bi odun kesan an bayii ti a ti bere eto yi, ipinle Ogun
ati ipinle Eko lati ti bere e, ti e ba si wo o bayii, o ti kaakiri orileede yi,
to si tun ti de awon orileede to sunmo wa. Awon ileese aladani naa n da si wa
lati se iranwo ti won ba lagbara. Bi won se n fun wa lowo naa ni won tun n fun
wa lawon ohun elo ta a fi n seranwo fawon araalu.
AWIKONKO: KI
NI E LE PE GEGE BI ASEYORI YIN LARIN OSU MERIN TI E GBA IJOBA EGBE YI?
GIWA: Aseyori
egbe yi naa ni aseyori mi. A ni agbekale ti a fi n yan olori ninu egbe wa. Bi a
bay an adari kan lonii, a ti mo adari ti yoo gbajoba lodun to n bo, ko da a, o
tun see se ka mo adari odun meji sasiko yi, agbekale egbe wa niyen.
AWIKONKO: ONA
WO GAN AN NI IJOBA N GBA RAN YIN LOWO?
GIWA: A fi ka
dupe lowo ijoba nitori pe ona to po nijoba naa n gba ran wa lowo nitori pe bi a
ba ni ka woo, iru eto ta a gbe kale yi, bi a ba ni ka loo gba ibi kan ti a ti
maa se e, dandan ni ka san owo lati lo iru ibe yen, sugbon ofe ni ijoba ni ka
lo inu ogba osibitu yi, to si tun je pe awon osise osibitu naa tun n sagbateru
wa, awon ni won n ba wa dawon eeyan lohun lai gba owo lowo wa. Nnkan ti a n pe
ni ifowosowopo niyen yato si owo ti a maa n da ninu egbe lodoodun, iyen annual
dues la maa n lo lati fi awon nnkan ti a n se yii. Awon ileese kan naa to tun n
ran wa lowo ni pe won n gbe owo kale lati maa fi se itoju fawon to ba nilo ise
abe, yala oju ni tabi aisan min in.
AWIKONKO: AWON
WO LO LE DARAPO MO EGBE YIN?
GIWA: Eni to ba
je asiwaju ninu ijo, to si ti setan lati maa se daadaa ni agbegbe to n gbe lo
le darapo mo wa.
AWIKONKO: AMORAN
YIN FAWON ARAALU
GIWA: Amoran mi ni pe ki won mu ilera ara won
lokunkundun nitori emi ko pe meji. Gbogbo eeyan lo gbodo mo pe ilera loro, ko
si seni to le ri oogun ko ma dagba se. idi ni yii ti won fi gbodo lo maa se
ayewo ara won loorekoore. E je ki n so fun un yin, egbe wa n se iranlowo fawon
ijoba ni, nitori pe eka eto ilera lo je okan pataki lara awon nnkan tijoba n
dojuko lati se, idi ni yii ti ninu won fi n sa lati torun bo, nitori pe owo to
n ba a lo po, idi ni yii ti won fi nilo awon ajo ati egbe bii egbe wa lati ba
won dowo po, ki won le rii pe gbogbo eeyan lo n je anfaani eto ilera.