“Pelu imo ati iriri
alailegbe ti gomina tele nipinle Anambra, Peter obi ni, yala ninu ise ijoba
tabi aladaani atawon imo to ti ni kaakiri agbaye, idi niyen ti mo fi mu un gege
bi igbakeji mi, ati pe ajpsepo wa yoo wulo dada fun ilosiwaju Nigeria.”
Ninu atejade kan ti
Otunba Gbenga Daniel, eni ti se oludari ipolongo ibo fun Alhaji Atiku Abubakar lo
ti fidi oro yii mule.
O te siwaju pe, awon
ohun amuye ti gomina tele nipinle Anambra ohun ni; lo mu egbe oselu PDP fowo si
i lati je igbakeji Atiku ninu ibo aare lodun to n bo.
O ni, “Ohun to mu Atiku
ati egbe oselu PDP yan Peter Obi' gege bi eni ti yoo dije-dupo Aare pelu e lodun to bo ni bi okunrin naa se wa
lara awon odo orile-ede yii ti won lami-laaka ninu iriri orisirisi, paapaa eyi
ti gomina tele naa ti ni ninu ise ijoba ati ti aladani.
O ni “Peter Obi ni imo kikun ti a ba n so nipa oro aje aladanla ati alaboode, yala nile yii ni abi loke okun; bee gege lo tun je eni ti imo e kun, ti a ba n so nipa eto isuna owo, eyi ti yoo sanfaani nla fun ilosiwaju orile-ede yii, paapaa niru asiko ti Nigeria wa bayii.
O ni “Peter Obi ni imo kikun ti a ba n so nipa oro aje aladanla ati alaboode, yala nile yii ni abi loke okun; bee gege lo tun je eni ti imo e kun, ti a ba n so nipa eto isuna owo, eyi ti yoo sanfaani nla fun ilosiwaju orile-ede yii, paapaa niru asiko ti Nigeria wa bayii.
O ni, ajosepo awon
mejeeji yii ni yoo da orile-ede yii pada si ona to ye, ti idagbasoke alailegbe
yoo ba eto oro aje wa, ti isokan yoo si wa pelu.
Ninu atejade ohun lo
ti so pe; ojo kokandinlogun osu keje ni won bi Peter Obi lodun 1961. Ileewe Christ
the King College, l’Onitsha lo lo, leyin e lo te siwaju lati kawe si i ni University
of Nigeria, Nsukka nibi to ti kawe gboye Bachelor of Arts in Philosophy.
Bakan naa lo tun kawe lorisirisi
lawon ileewe wonyi: Lagos Business School, Harvard Business School, London
School of Economics, Columbia Business School, Institute of Management,
Switzerland, Kellogg Graduate School, Oxford University and Cambridge
University.”
Ti a ba n so nipa ise
ijoba, opolopo eka ileese ijoba lo ti
sise pelu, lara won ni: okan lara awon to n sasaro lori eto oro aje fun ileese Aare
(Member, Presidential Economic Management Team) , igbakeji alaga fun apejo awon
gomina (Vice-Chairman, Nigeria Governors' Forum); Alaga fun awon gomina apa iha
Guusu-Ila-OOrun (Chairman, South-East Governors' Forum), bakan naa lo tun ti se
gomina ipinle Anambra ri.
Oguna gbongbo kan ni Peter
Obi, eni to ni imo kikun nipa ise ijoba ati ise aladaani ni pelu. Oun naa tun ni
alaga fun ileese Board of Security and Exchange Commission (SEC); bakan naa lo
tun je alaga tele fun awon ileese yii; Fidelity Bank PLC; alaga tele ni banki Guardian
Express Mortgage Bank; oun naa tun ni alaga Future Views Securities; alaga tele
fun Paymaster Nigeria; alaga tun ni ni Next International Nigeria; oun naa tun
ni alaga won tele ni banki Guardian Express Bank PLC; oga agba tun ni lawon
ileese wonyi: Chams Nigeria PLC;, Emerging Capital: ati Card Centre PLC.
Lara awon ti yoo dije
dupo aare lodun to n bo ni Alhaji Atiku Abubakar, eni to ti figba kan je
igbakeji aare orile-ede yii ri laye ijoba Obasanjo. Oun naa yoo dije-dupo aare lodun
2019, bee lo si ti mu igbakeji e bayii, Peter Obi, omo ipinle Anambra, eni to
ti se gomina tele ri nipinle ohun.