OSIBITU TI AWON ALAISAN MOLE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, October 12, 2018

OSIBITU TI AWON ALAISAN MOLE


Ko din ni meje lawon alaisan foniku-fola-dide (sickle sell anaemia) ti ileewosan meji otooto nipinle Anambra ti ti mole latari bi won ko se rowo san latari iwosan ti won fun won.
 
Alaga egbe kan to n ri soro awon to ni aisan naa, (People Living with Sickle Cell Disorder (PLSD)), Arabinrin Aisha Edward lo fidi oro yi mule lojo Tosde to koja yi lasiko to n bawon oniroyin soro lagbegbe Nanka to wa nijoba ibile Orumba North nipinle Anambra.

Egbe naa so pe ona ti ko bofin mu lawon ileewosan naa gba lati ti awon alaisan naa mole, ati pe iwa odaju lawon ileewosan naa hu, won ko si laani eleran ara bii ti won.

O loun lo sileewosan kan lati wo awon to ni aisan naa nibe, ti won si n je ko ye oun pe awon alase ileewosan naa ti awon eeyan mole, won ko fi won sile lati lo sile won leyin ti won gba itoju, latari owo tabua ti won ko fun won, eyi ti won ko ri san an.

O ni igbese lati da si oro naa ti bere, ati pe oun mo pe iru awon eeyan bayii si ku lawon ileewosan kookan bee, sugbon toun yoo sewadi won lati tese ofin oro naa.

PÍN-IN KÁÀKIRI