Alaga egbe Igbimo Agba Yoruba, Dokito Muiz Omonayajo ti so pe
erongba ti won fi da egbe naa sile yato patapata si erongba ti won fi da egbe
Afennifere sile. Lai pe yi ni Dokito Omonayajo soro yi lasiko to n b’AWIKONKO
soro ninu ile e to wa niluu Abeokuta. Nibi iforowero naa lo ti so nipa irin ajo
aye e, ati bo se di alaga egbe naa nipinle naa. Bakan naa lo tun so nipa Egbe
OPC ti Aare Ona Kakanfo, Otunba gani Adams da sile ati ajosepo egbe naa. E ka
bi iforowero naa se lo.
OMONAYAJO: Oruko mi ni Dokito Muiz Ajani
Adeleke Omonayajo, alaga Igbimo Agba Yoruba nipinle Ogun.
AWIKONKO: Ka too tesiwaju, nje a le mo die nipa irin
ajo yin ki e too di alaga?
OMONAYAJO: Ti e ba fee mo itan nipa igbesi aye
mi, e maa nilo lati se iwe itan nla meji, to maa kun repete. Opolopo mo mi,
sugbon o ni iwanba nnkan ti won mo nipa mi, sibe, maa so die ninu e fun yin
nipa bi mo se lo sileewe. Ilu Abeokuta ni won ti bi mi ladugbo Ilugun. Omo
Ilugun nile Agbunrin ni baba mi, nitori pe agboole Agbunrin yen, awon oni-Sango
lo po nibe, nitori esin Musulumi toun gba, lo se kuro nibe lo si odi keji. Keu
la maa n koko ke ninu idile ka too lo bere ileewe. Baba-baba mi je Oke Ona,
iya-baba mi je Egba Alake; Baba-iya mi je Gbagura, Iya-iya mi je Owu, origun
mereerin Egba ni mo fi tan. Ileese irina oju-irin ti orileede Naijiria (Nigerian Railways) ni baba mi ti sise, nigba ti won gbe baba mi lo siluu
Guso ti won so di Gusau bayii, ibe ni mo ti bere ileewe alakobere nileewe Aguda
(Catholic School), ibe ni won ti se iribomi fun mi.
Bi baba mi se gbo, lo ti mu mi kuro nibe, to si mu mi lo si
ileewe Anglican. Ibe ni mo ti nife si esin Kristeni. Nigba ta a gbominira ni
baba mi pada wa siluu Abeokuta. Igba ti baba mi pada sile ni mo sese wa a bere
ileewe giga, iyen Methodist niluu
Igbo-Ora. Igba tawon to mu esin igbagbo wo Naijiria (Missionaries) fe e pada si orileede won, ni won fa ileewe naa le
awon olori niluu Igbo-Ora lowo, ibe ni mo ti bere esin Kristeni ni pereu,
nitori pe oga ileewe yen feran mi, o si je elesin igbagbo. Igba ti mo kuro
nibe, mo lo si Federal School of Science ni Onikan, l’Eko, ibe ni mo ti kuro ti
mo fi loo sise ni Western Region, ileewe yi ni mo tun pada si lati loo sise
Tisa, ko too di pe mo lo si Yunifasiti lati look o eko nipa Oogun (Medicine). Bi mo se wa nileewe yi, ni mo
tun n sise peepeepee, ti ko si di ara won lowo. Mo sise ni Leonart to wa ni
Ojota niluu Eko, mo sise ni National Bank
Marina.
Ko pe ti mo jade ni Yunifasiti, ti won fi da ipinle Ogun sile,
ipinle Kwara ni mo ti loo se Agunbaniro mi, mo isse nibe, mo si gba awoodu,
nitori pe mo gbe eto kan kale ti mo pe ni Baby
Week Show, eyi ti mo fi n se itoju awon araabule yen. Igba ti mo kuro nibe,
ni osibitu ti mo ti sise nigba naa gbe mi lo sodo Oloogbe Olabisi Onabanjo gege
bi dokito won fun odun merin, igba to ya, ti Onabanjo kuro nipo, mo tun je
dokito fun Jenera Oladipo Diya, ko too di pe won gbe mi lo siluu Ilaro. Igbe ti
mo kuro nibe ni won tun gbe mi wa si Ministry
gege bi akowe Mo ti sise ni ileewosan ijoba to wa ni Sagamu labe Baba
Ogunnekan. Igba ti oga mi feyinti, won fi mi se alakoso fidihe gege bi eleto
ilera nipinle Ogun (Ogun State Acting
Chief Medical Officers). Mo tun lo si ASCON
(Administrative Staff College of Nigeria)
ni Badagry nibi ti mo ti ko Research
Methodology.
Igba to ya, won fi mi se Head
of Planning Division, ibe ni mo wa kawon banki agbaye (World Bank) to o de
lati ya awon ipinle lowo lati maa fi seto ilera, emi ni won ti sibe lati mojuto
o. Awon banki agbaye yi ni won fun mi niwe eko ofe lati loo kekoo loke okun,
iyen University of Leads, Britain. Igba ti mo setan nibe, mo pada
sile, bi o se n de ni won fi mi se Director
Planning Research and Statistics nipinle Ogun, emi ni mo je eni akoko. Ibe
lawon oyinbo Japan tun ti de, ti won fun mi ni eko ofe niluu Tokyo, igba ti mo
de, ijoba apapo yan mi gege bi okan lara awon to maa lo so asoyepo lati gba owo
ele ni banki agbaye (World bank Loan), iyen ni Washington DC. Igba yen, Dokito Makanjuola ni alakoso ni Ministry
of Health, ti emi si je alakoso ni eka eto ilera tipinle Ogun (Ogun state Ministry of Health).
Leyin ta a setan nibe, ta a de, won ni ka wa gba eyawo naa,
mo wa a ri pe ele (interest) ti won
fe e gba lori eyawo yen ti po ju, mo so fun won pe owo ti won n fawon ara oke
oya, pe kawa naa gba, iyen African Development Bank Loan, idi ni yii ta a fi so
gbogbo awon ileewosan to wa nipinle Ogun di jenera (General Hospital). Ibi ta a ti lo soro nipa eyawo yen niluu Abidjan
ni won ti so pee mi ni ki n je alakoso (Project Manager). Asiko yen aawo wa
laarin emi ati Gomina Sam Ewang nitori pe ona to fe e ka gba ko ba ilana awon
to ni owo yen mu, won si ti towo bowe adehun pelu emi, ti won gba mi gege bi
osise ti kii se osise ijoba taara (secodnment), eyi ti ko ye opolopo awon eeyan.
Won dite nigba naa, sugbon Olorun ti mi leyin. Mo gbe won lo si kootu, ile ejo
si pase pe ki won san gbogbo owo ti won je mi, won si san an. Ibe ni mo ti
feyinti.
Leyin ti mo feyinti, mo loo sinmi fungba die, ko too di pe mo
loo se oselu. Igba ti mo kuro nidi oselu ni won wa a pe mi pe ki n wa a se
alaga Igbimo Agba Yoruba fun won nipinle Ogun, iyen lodun 2011. Awon agbaagba
ile Yoruba ni won pe mi pea won fe ki n tun aarin awon Yoruba se nipinle Ogun. Ni
bayii, mo ti n ronu lati fa a le awon Ijebu lowo, nitori pe bi Ijebu ba se e,
Egba lo kan. Ojogbon Adedeji lati United Nations ti se e rii.
AWIKONKO: Gege bi alaga
Igbimo Agba Yoruba nipinle Ogun, kinni in egbe yi da le lori, ati pe ki nidii
ti won fi da a sile?
OMONAYAJO: Nnkan ti Igbimo Agba Yoruba duro le
lori naa ni won fi da a sile, a ko fe ki iya je omo Yoruba kankan, a si tun fe
e ko awon omo Yoruba nipa iwa omoluabi, ka fowosowopo, ka si le nilosiwaju,
nitori pe agbajowo la fi n soya. Koko to wa nibe ni pe a ko gbodo pa iwa
omoluabi wa tii, iyen nip e ka feran enikeni wa, ka si tun se otito pelu iwa to
dara. A n kede pe kawon omo kekeeke ni ibowo fagba atawon asiwaju, nitori pe
Olorun gan an so pe ka bowo fawon alase,nitori pe oun loun fi won sibe.
AWIKONKO: Ki lawon
aseyori yin laarin asiko yii?
OMONAYAJO: Mo ti se opolopo awon aseyori. A ti
se awon kan ti Olorun ti fun wa se, a ti se awon kan ti a ko tii pari, a si tun
n se awon kan lowo. Nile Yoruba, isoro ta a ni ni pe gbogbo eeyan lo fe e je
olori, kii sii se gbogbo eeyan ni Olorun da lati se olori. Eni kan soso lo le
je olori kawon toku le gbaruku tii. A ti wa atunse si opolopo ede-aiyede to n
sele nile Yoruba, awon omo wa ti won nisoro la ti sise lori e. A ti jokoo lori
awon igbese to ye ka gbe lori awon omo wa to kawe gboye, sugbon ti won ko rise
se. Bi a ba ni ka woo, gbogbo nnkan ko le se e se tan lojo kan soso, die-die
ni, sugbon ebe la n be ijoba ki won le ba wa gbe ise jade fun won.
AWIKONKO: Ki ni ajosepo
egbe yi pelu egbe Afenifere?
OMONAYAJO: Bi e ba wo egbe Afenifere nigba kan,
e maa sakiyesi pe o pin sona meta abi merin, sugbon ti ko sele laarin Igbimo
Agba Yoruba, eyokan soso ni wa. Eekeji nip e, oselu ni won fi da egbe Afenifere
sile, a ko fi oselu pile egbe Igbimo Agba Yoruba. A wa ko so pe keeyan ma se
oselu, sugbon to ba de inu Igbimo Agba Yoruba, o ni lati gbe oselu segbe kan, o
si gbodo fowosowopo peluu wa. Nitori atunse ati atunto la fi da egbe Igbimo
Agba Yoruba sile, eni to ba si darapo mo wa gbodo je eni to n fe atunse laarin
gbogbo awon oloselu. Omo iya kan soso ni wa, a ko si gbodo maa ja.
OMONAYAJO: Ipinle mewaa lo n se egbe Igbimo
Agba Yoruba, awon naa ni Eko, Ogun, Oyo, Osun, Ekiti, Ondo, Kwara, Edo ati Delta
nitori pe omo Oduduwa ni gbogbo wa. Ajosepo to dan monran lo wa laarin wa. Ipinle
kookan lo ni ileese egbe, a si tun ni olu-ileese to so wa po. Yato si eyii, a
tun ni eka sawon ilu Oyinbo kaakiri, bii Britain, Canada, Uk, US ati bee-bee-lo.
AWIKONKO: Kinni ojuse
egbe yi ninu eto isejoba orileede yi, paapaa lawon ipinle ti e ni eka sii, ati
pe ki ni ajosepo egbe yi peluu egbe Oodua Peoples’ Congress (OPC) ti Aare Gani
Adams da sile?
OMONAYAJO: Egbe OPC ti Aare Gani Adams da sile
je gege bi eka ninu egbe Igbimo Agba Yoruba. Won duro gege bi egbe eleto aabo
fun omo Yoruba, bo tile je pe awa ko jagun mo, a ko si gbadura fun ogun. A ko
fe ki ijoba ri wa gege bi egbe alatako, tabi egbe to n bu enu ate lu ijoba,
nitori pe ilosiwaju la n wa. Alaafia ile Yoruba, paapaa orileede Naijiria la n
wa. Yoruba kii fi ada ati ibon ja, opolopo la maa n lo lati fi ja fun eto wa. Ko
digba ta a ba bere sii pariwo kaakiri, tabi fa wahala, ki won too le mo pe inu
n bi wa. Bi e ba wo asiko ogun Biafra, e maa sakiyesi pe Yoruba ko yo ibon tabi
ada, opolo wa la fi yanju ogun naa. Ti e bar anti nigba naa, Oloogbe Obafemi
Awolowo soro nigba naa pe a le awon ota wa, a tun n fun won lounje, o rii pe
ounje ti won fun won yen lo pana ogun, kii se iye ota ibon. Ogbon la fi n se
ohungbogbo ta n se.
AWIKONKO: Awon wo ni
won n se egbe Igbimo Agba Yoruba, ati pe awon wo lo le darapo mo egbe Igbimo
Agba Yoruba?
OMONAYAJO: a ti se atunse iwe ofin (constitution)
wa. Eni to ba je okunrin, o ni lati je omo ogota odun, ta a si rii pe o ni
laakaaye, o si gbogbo faramo gbogbo ilosiwaju ta a n wa, iru eni bee le darapo
mo wa. O maa foruko sile, aa si san owo iforuko sile, ka too le gba a wole. To ba
je obinrin, o gbodo ti pe aadota odun. Awon to ba fe e darapo mo wa gbodo rii
pe oun setan lati maa se gbogbo eto e to ba ti n to asiko. Kii se tipatipa la
fi n gbaayan wole, eni to ba fe e darapo gan an, a ni lati wo iru eni to je.
AWIKONKO: Amoran yin
fawon omo Yoruba, paapaa ijoba orileede Naijiria?
OMONAYAJO: Irepo ati ododo ni maa fi ranse
sawon omo Yoruba, paapaa awon omo Naijiria pelu ara won. Ki won ma se
imotara-eni nikan, nitori pe ibi ti otito ati ife ni Olorun n wa. Amoran mi fun
ijoba ni pe ki won se daadaa, ki won si ranti pe won maa kuro nibe to ba di
ola, nitori pe ohun teeyan ba se lonii n bo wa di itan. Ki won faaye sile fawon
odo naa lati di awon ipo kan to to si won mu, nitori pe pupo ninu won lo logbon
lori, ti won si ni agbekale ti won lati mu idagbasoke ba orileede, ati pe
nitori pe won ko mo eeyan to wa nipo ni won ko se ri ipo di mu ninu eto
isejoba. A fi ki ijoba tete wa ona lati da ise sile fawon omo to n kekoo jade
yii, tabi ki won wa ona ti owo fi ma maa wole sapo awon omo yii nitori pe owo
ni won a fi maa se nnkan ti won ba fe e se. ko si nnkan to buru ninu ki ijoba fawon odo
laaye lati sejoba, nitori pe won ni omode gbon, agba gbon ni won fi da Ile-Ife.
AWIKONKO: Nje e
nigbagbo pelu asiko olaju ta a wa lonii pe ayipada tun le de ba Asa ati Ise Yoruba?
OMONAYAJO: Pelu awon nnkan temi n ri nipinle
Ogun, ayipada ti de ba asa Yoruba, bi e ba ri Komisana foro Asa ati Isese
nipinle Ogun, iyen Basorun Muyiwa Oladipo bo se n se bebe nipa gbigbe Asa
Yoruba laruge. A ko si le ki oun nikan lai ki eni to fi sibe, iyen Gomina
Ibikunle Amosun. A tun n rowo Ojogbon Wole Soyinka naa nipa Asa. Awa gan gan la
ko ni faaye sile pe ko pare, nitori naa bi won ba ti pe wa sii, a fi ka sunmo
won. Asa wa ti n pada si ti tele, nnkan to ku ni pe kawon omode bowo fawon agba
won. Igbimo Agba Yoruba ta n so pe a n se yii, awon Oba alade gan an lo ye ko
je Igbimo Agba Yoruba, oludamonran lo ye ki awa je, sugbon nitori pe ijoba lo n
dari awon Oba, o niwonba ta a le pe awon Oba sii, bo tile je pe aaye wa lati
maa gbamonran lodo won, ki ilosiwaju ba a le maa po si.