OJELU LAWON OLOSELU TA N NI LATI ODUN 2007 - AWOLOWO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 31, 2018

OJELU LAWON OLOSELU TA N NI LATI ODUN 2007 - AWOLOWO

Gbajumo sorosoro ori redio ati telifisan nni, Komureedi Olumide Awolowo ti rawo ebe sawon omo orileede Naijiria, paapaa awon omo ipinle Ogun pe ki won foju sile daadaa lati dibo fawon oloselu ti won ba wa n ba won fun ibo lodun 2019.


Olumide Awolowo, eni tawon eeyan tun n pe ni Gedu Master so pe etanje lo po ju lenu pupo ninu awon oloselu ta a ni lorileede Naijiria, to si je pe nnkan ti won maa je ni won n ja fun un, bi owo se maa wole sapo ara won ni won n wa kaakiri, idi ni yii ti won ko fi gbodo gba won laaye ninu ijoba lodun to n bo.

Awolowo to filuu Abeokuta sebugbe lo soro naa losan onii lasiko to n b’AWIKONKO soro latari ipinu e lati jade dupo omo ile igbimo asofin ipinle naa labe egbe oselu Alliance for Democracy, AD, eni to fe e soju ekun Guusu Abeokuta akoko ninu idibo odun 2019 to n bo lona.

“Gbogbo eeyan lo mo mi pe ogbontarigi sorosoro ati pedepede lori redio ati telifisan ni mi looto, sugbon sibe, oloselu ti kii da’le ni mi, oloselu ti ko tori nkan to fe e je ba nnkan to fe e je je. Lodun 1998, oselu awaarawa ta n se lo yi, emi ni mo da egbe Student Alliance for Democracy (SAD) sile, ta n sise fun Oloye Olusegun Osoba to je gomina ipinle Ogun nigba naa.

“Pataki ta a fid a egbe naa sile ni pe gbogbo awon akekoo to ba fe e ri gomina nigba naa, inu egbe naa ni won maa gba rii, emi ni gomina maa n ran si won. Lati ibe ni mo ti bo sidi ise redio, ise redio si wa a gba asiko lowo mi, ti ko je ki n raaye se oselu daadaa nigba naa.

“Nnkan to mu ki n fi gbogbo ara wonu oselu ni pe pupo awon ta n gbe sipo yi ni won n ba ise wa je, kaka ki won maa je kise oselu rorun nipa awon ileri ti won n se lasiko ipolongo ni won maa pa ti bi won ba de ipo tan, to je pe imo tara won nikan ni won a maa se.

“Nibi ta a se de, a ni oruko rere (integrity) laarin ilu, mo si ni iwa gidi lawujo, awon nnkan to si maa soro fun mi lasiko ti ipolongo ba bere niyen. Emi kii se oloselu ti yoo maa lo dobale bebe kaakiri nitori pe oloselu to ba sese lo n dobale bebe ki won le dibo fun, nnkan to maa je lo n wa, ole si ni iru won.

“A ni nnkan kan lorileede yi, paapaa nipinle Ogun, awon asoju ti ko dara, awon ti ko kun oju osuwon, asoju to je pe owo ati nnkan ti won maa je ni won n wa kaakiri. Mo le fi gbogbo enu so o pe latigba ti a ti n se oselu lorileede yi pe ijoba meji pere lo kun oju osuwon, iyen ijoba to kan mekunnu lara.


“Ijoba Oloogbe Oloye Olabisi Onabanjo ati ijoba Oloye Olusegun Osoba, idi ni pe ki won too de ipo yen, won ti wa laarin awon mekunnu, won ti sise oniroyin to je ilekun laarin ijoba atawon araalu, won ti mo iya to n je awon araalu, idi ni yii ti won fi se daadaa. Lati odun 1999 ta a ti gba ijoba awaarawa pada titi di odun 2003 ti Oloye Osoba kuro nipo, awon oselu ni won wa nipo. Saa akoko ijoba Otunba Gbenga Daniel, awon oselu ba won se ijoba, sugbon lati saa keji titi di asiko ta a wa yi, ojelu ni gbogbo won patapata nitori pe won wa a fowo sowo ni.

Nigba to n soro lori idi to fi fe e jade dupo naa, paapaa labe egbe oselu AD, Olumide Awolowo so pe “Awon eto kan wa tawon araalu gbodo maa je, sugbon won ko rii, nitori pe won ko rawon ti yoo ba won pariwo e sita, ni won ko ti ri eni ti yoo gbe aba naa jade, eyi ti yoo je ki won so o di ofin lati mu irorun de ba mekunnu.

“Won de ipo, won tun n so pe mekunnu ko gbodo ra taya moto tokunbo mo, se mekunnu ti ko ri owo osu gba, se o le rowo ra taya tuntun, to ba ti e wa ri owo naa gba tan, eelo lowo osu e to fe e fi ra a?, o fi han pe oto ni iya to n je wa, oto ni nnkan tawon oloselu yi n se.

“Bi n ba ni anfaani lati de ipo yi, awon anfaani wa ti a maa se fawon araalu, eyi to je lati ara eto abadofin. Ona ta a le fi gba ran mekunnu lowo nitori pe awa naa ti la ipo yen koja ri la maa gbe kale. Awon eto kan wa ta a ti se kale pe ba a ba depo naa tan, awon eto kan ti wa la fe e gbe kale, eyi ti yoo je kawon akekoo, paapaa awon ti won ko lagbara lati ran ara won lo si  ileeko giga yoo je.

“Eto ilera naa wa loto, sugbon mi o fe e so o sita kawon min in ma lo muu lo. Nnkan to ba mu awon eroja eto idibo de awon abule ati igberiko to jinna, leyin idibo, mudunmudun oselu ijoba awaarawa naa gbodo de be lati janfaani e. lara nnkan ta a fee mojuto niyen. Oludibo gbodo ri ere idibo won ba a ba ti wole.

“Egbe Afenifere ni Alliance for Democracy, AD ni mo pada sib o tile je pe mo ti wa nibe lati ogun odun seyin, ko si nnkan meji ti mo fi pada sibe bi ko se ti awon eto ati ilana egbe naa eyi to je pe fawon araalu lo wa fun. Egbe AD ko faaye gba magomago, egbe APC ni mo ti kuro wa si AD. Ko si nnkan meji to je ki n kuro ninu egbe APC bi ko se pe pupo ninu awon to n du ipo nibe, wonbiliki-wobia, ole ni gbogbo won.

“Iru awa ta a lo lowo lati na fawon eeyan, sugbon ta a ni opolo lati fi tun ilu se, a a le ri anfaani nibe sugbon awon to lowo lowo lati na fawon araalu, to si je pe atije ni won ba debe, awon le maa ri nibe. Egbe AD kii se egbe ti won le fowo ro ti seyin ninu egbe oselu lorileede Naijiria, paapaa nipinle Ogun.”


Bakan naa lo tun soro nipa oro owo osu to kere julo tawon osise orileede yi n ja fun, Olumide Awolowo so pe “Ni odun 2015 ni mo ti soro pe ko si nnkan ti ijoba Aare Muhammadu Buhari fe e se fun omo Naijiria. Emi o dibo fun un nitori pe asorose kii soro danu, gele ti won si ti wole la ti n ri bi won se n sejoba won radarada.

“Mo so fawon eeyan pe bijoba yi se maa se titi to maa fi ku die ki asiko idibo min in too de. Nigba naa mo so pe to ba maa di inu osu kefa si osu keje odun pe ijoba ma maa gbe igbese lati fowo kun owo osu awon osise, oun ni won si maa fa titi di osu kokanla si osu kejila ti ipolongo idibo yoo fi bere. Bi mo se so o nigba naa lo se n sele bayii.

“E maa rii pe leyin-o-reyin, won maa gba tawon osise, sugbon to ba wa a die yin idibo, ko si ani-ani, bentiroolu maa tun gbe owo lori, e je ki won look o deeti oni sile. Ijoba yi maa fe tan awon eeyan lati fowo kun owo osu, sugbon leyin ibo ti won ba pada wole, won a fowo kun owo epo.

“Eto awon osise ni won n ja fun un, a ko si gbodo fi dun won ipa ti awon osise nko ko kere. Oogun won ni won n ja fun, ko si gbodo gbe. Osise to sise fun ogbon ojo pelu ise asekudorogbo, egberun mejidinlogun ni won n gba. Awon oloselu to je pe bii wakati meta ni won fi n sise, to si je pe eemeji si eemeta lose ni, ogun milionu si ogbon milionu naira ni won n gba, e je ka gbe e yewo sira won.

“Looto, eto won ni won n ja fun nitori pe ijoba maa pada gba fun won gbeyin ni, lati tan won je si ni gbigba naa. Nitori naa won gbodo si opolo won sile.

Nigba to n rawo ebe sawon omo ipinle Ogun, paapaa ekun Abeokuta South to ti fe e jade, o so pe eto idibo asiko yi kii se oro egbe oselu, nitori naa ki won dibo fawon eeyan to n jade.

O ni ki won ma se gba fawon oloselu to je pe nitori ipo ni won se n kuro niluu Amnerika ti n gbe, lati wa a dupo ni Naijiria, ti won ko si mo iru iya to n jawon eeyan.

PÍN-IN KÁÀKIRI