Bi
iroyin to n lo n lo kaakiri igboro ipinle Ogun, paapaa orileede Naijiria lasiko
yi nipa pe gomina Ibikunle Amosun fe e fi egbe oselu APC sile lo sinu egbe
oselu min in, a je pe afaimo ki egbe oselu APC naa ma pada tuka.
Fawon
to ba mo bi oselu ipinle Ogun se n lo si, paapaa ninu egbe oselu APC, won a mo
pe ko si nnkan meji to n da wahala sile bi ko se ti idibo pamari sipo gomina to
waye lai pe yi, ti won ni Dapo Abiodun lo wole, eni ti Gomina Amosun ko figba
kan gba ti e.
Onarebu
AbdulKabir Adekunle Akinlade ni Gomina Amosun fa kale lati gbe ijoba fun,
sugbon ti won ni awon kan ko faramo, ati pe won ni se ni Gomina Amosun n da ase
egbe oselu naa pa.
Lojo
Monde ose to koja yi ni Gomina Amosun ti leri nita gbangba pe oun yoo fi gbogbo
nnkan toun ni bawon alatako oun ninu egbe naa ja, nitori pe orisirisi iro ni
won ti loo pa moun lodo Aare Muhammadu Buhari niluu Abuja.
Ni
bayii, a gbo pe nibi ipade ti Gomina se pelu awon omo egbe to je ti e lo ti je
ko ye won pe bi igbimo amusese NWC egbe naa ba ko lati fi oruko Adekunle
Akinlade toun fe dipo oruko Dapo Abiodun ti won ko, se loun yoo kuku fegbe naa
sile fun won.
Bawon
kan se n so pe egbe oselu Accord ni Amosun n gbero lati lo, bee lawon kan n so
pe egbe oselu Accord ko le faaye gba a lati wa a dabaru eto ati ilana egbe won.
Bi
nnkan ba se n lo l'AWIKONKO yoo mu wa fun un yin lati mo. Ekunrere n bo lai pe.