Ilu Eko ni Aare Muhammadu Buhari ti soro yi lasiko to n bawon eeyan soro nibi ayeye eto okoowo odun karundinlogorin (75th) eyi ti Island Club se lojo Monde ana.
O ni yoo gba ju saa isakoso kan lo lati le se awon atunse to ye lati mu orileede Naijiria lo si ipele to ye ko wa, ati pe lati yoo gba ju idibo eekan soso lo ki ileri toun se too le di mimuse.
Buhari so pe ayipada tijoba oun seleri kii ayeye ojo kan soso, bi ko se pe nipele-nipele ti yoo gba akoko ni, nitori naa kawon omo Naijiria dibo yan oun leekeji fun odun merin min in.
Bee lo so pe lai pe lawon igbese toun ti gbe laarin odun meta aabo lati mu atunse deba orileede Naijiria gege boun see seleri e ko ni pe ti yoo fi bere sii farahan.
No comments:
Post a Comment