Ti
a ba n so nipa agba oloselu to mo tinu-tedo nipa oselu, paapaa eni to tun je
okan lara awon to da egbe oselu Alliance for Democracy, AD sile lorileede yi,
ati okan lara awon omo egbe Social Democratic Party lakoko ti won da sile, odu
ni Onarebu Akinyele Sarafadeen Ogunwoolu je kii saimo foloko, oun naa ni alaga
egbe oselu Allied Congress Party of Nigerian, ACPN nipinle Ogun.
Eni
to ti figba kan je okan lara awon omo ile igbimo asofin ijoba ibile guusu
Abeokuta nipinle Ogun lodun 1991 ati alabojuto ijoba ibile Abeokuta South so pe
oun loun sagbateru eto idibo to gbe Aremo Olusegun Osoba wole gege bi gomina
ipinle Ogun lodun 1991, to si je pe Onarebu Dare Gbolahan tawon jo je omo
agboole kanna lo gba ogo yen nitori pe moto e la lo lati fi se ipolongo lodun
naa. Oruko Dare Gbolahan lo wa lara moto tawon lo, eyi lo je ki Osoba ro pe
Gbolahan lo sagbateru e, to si lo ba leyin ojo karun.
Onarebu
Ogunwoolu ba AWIKONKO soro nipa ojo ti inu e baje ju nile aye. O so pe ojo
ti baba oun so pe oun ko ni le tesiwaju lati lo sile iwe giga mo, lojo naa loun
lo fibinu gbe gamale20 mu, to si ku die ki iku gbemi oun.
O
soro naa laipe yi lakoko to n bakoroyin wa soro fun ti irin ajo ogota odun e
loke eepe nibi tawon amuludun leka oselu bii Onarebu Allen Taylor ti pejo lati
baa se ayeye naa. Nibe ni Baba naa ti so orisirisi oro nipa igbesi aye e ati bi
o se wonu oselu lorileede Naijiria.
“Ojo
ti baba mi pemi lati salaye fun mi pe oun ko ni agbara lati ranmi lo sile iwe
giga, nitori naa, ki n duro lori iwe eri eko girama ti mo ni.” Baba to sese pe
ogota odun naa so pe, boun se kuro niwaju baba oun, gamale20 loun lo gbemu. O
ni iya agba kan lo ri oun boun se n se lojo naa, to si fura pe nnkan ti sele
soun.
"Nigba
ti won beere oro lowo mi ti mi o dahun, lo ba je ki won mo pe mo ti gbe majele20
je, loju ese ni won sare gbe mi lo si osibitu Lesi to wa ni Isabo, Abeokuta,
nibe ni dokita ti so pe ko si atunse mo, sugbon opelope baba kan ti won n pe ni
Sikiru Salami lo so pe ki won gbe mi lo si Jenera to wa ni Ijaye nibi ti won ti
dokita Oyinbo kan ti so pe ki won lo wa agolo oogun ti mo mu yen wa, to si fi
se ayewo lati toju mi."
O
so pe baba oun bo tile je pe ko kawe pupo, bee ko si lowo lowo, sugbon o je gbajumo
tawon eeyan n kan sara si nitori iwa omoluabi to fi n ba awon eeyan se po, eyi
lokunrin naa so pe o wu oun lati darapo lati se oselu, ki ipinu toun ni forile
ede yi le wa si imuse.
Bakanna
ni Ogunwoolu tun soro nipa ojo ti inu e dun ju nile aye, o ni oun ko le gbagbe
ojo ti won foun ni iwe eri eko ofe lati kawe jade ile eko giga, iyen lodun
1970. O so pe ojo malegbagbe lojo naa je ninu igbesi aye oun nitori pe oun ti
roo pin pe oun ko le tesiwaju mo ninu eko. Baba to se iranlowo nigba naa lo pe
ni Oloogbe Emmanuel Abisodun Odumosumbo.
Nigba
to n soro lori bo se wonu oselu atawon ipa to ti ko, o ni oun ati Oloye
Arabinrin Titilayo Ajanaku, Ahmed Akindele atawon agbaagba kan lawon jo bere
oselu, to si je pe egbon Aare tele ri lorileede yi, Oloogbe Musa Yar’Adua lawon
jo wa ninu egbe kanna lodun 1987, iyen egbe Peoples Front of Nigeria, PFN.
Lori
idibo gomina lodun 2019 nipinle Ogun, awon eeyan so pe Yewa lokan, bo tile je
pe oun ko le so bi won ti pin, nitori pe ona meji ni won n gba pin Gomina
ipinle Ogun, iyen Ijebu ati Egba Province, atipe enikeni to ba darapo mo egbe won,
awon se tan lati gbaruku tii, ko si wole.
O
ni awon Egbado gan an ni isoro ara won nitori pe lodun 1976 ti won fee dibo
gomina laarin Olabisi Onabanjo ati Soji Odunjo to je omo Egba ati Yewa, awon
Egbado, kaka ki won fi ibo won gbe Soji Odunjo wole, won da ibo si fun Bisi
Onabanjo lati se gomina eleekeji. Latigba naa ni won ti n so pe Yewa lo kan,
Egba lo maa se, Yewa lo kan, Ijebu lo maa se.