Alaaji
Adekunle to tun je alase ati apase ileese Concord Real Estate lo soro naa losan
onii lasiko to n gba aami eye gege bi okan lara awon to n gbe ise iroyin laruge
lorileede Naijiria.
Alaaji
Adekunle to ti figba kan ri sise nileese iwe iroyin Concord ti Oloogbe MKO
Abiola da sile nigba aye e, bee lo tun ti sise lawon ileewe iwe iroyin min in
ko too bere ise ti e nipa ile tita ati mimu idagbasoke bawon ilu kaakiri.
Nigba
to n dupe lowo alaga egbe asojukoroyin, NUJ Correspondents' Chapel, Komureedi
Wale Adewumi, Alaaji Adekunle so pe inu oun dun fun aami eye naa nitori pe oun
ko lero pe won le pon oun le lasiko yi, bo tile je pe orisirisi aami eye loun
ti gba.
Komureedi
Wale Adewumi ninu oro ti e so pe kii se pea won dee de fun Alaaji Adekunle ni
aami eye naa, bi ko se awon ipa to ti ko ninu egbe oniroyin nipinle Ogun, yato
si pe o ti fise naa sile tipe, sibe awon ko gbodo ma gboriyin fun un.
Lara
awon to wa nibe ni Dokita Tony Ozemoya; Baala ilu Owu, Abeokuta atawon
amugbalegbe e, to fi mo awon omode e.